26-1025 Ìgbàgbọ́ #1

Eyin olooto nínú Kristi Jésù,

Asiko to logo ni èyí tí a ní. A Maa nwà ni ìfojusona ńlá lọ́sẹ̀ kọ̀ọ̀kan bí a ṣe ń kó ara wa jọ po yíká Ohùn Rẹ̀. Ọkàn emi wa bale. A mọ̀ Ẹni Tí Ó jẹ́ ni pato. A mọ̀ ohun Tí Ó jẹ́ pato. A mọ̀ ẹni tí a jẹ́ ni pato; a je ìdílé ńlá kan PẸ̀LÚ RẸ̀!

“Ó fifún ènìyàn láti jẹ́ ọlọ́run kekeeke.” Nítorí pé Òun ni Olorun Baba Agba, ó sì ṣe ènìyàn ní ọlọ́run kéekeeke, nítorí náà ko da wà fúnra Rẹ̀ mi gege bi tatijo, Ó wà pẹ̀lú ìdílé Rẹ̀. Iyen, Elah, Elah, Elohim ni. Ní báyìí Ó jẹ́ Jehovah. Jehovah, tí ó túmọ̀ sí, “Ẹni Tí Ó wà pẹ̀lú ìdílé Rẹ̀.”

Ìyàwó Rẹ̀ ń di pípé nípasẹ̀ Ohùn Jehovah Fúnrarẹ̀. Ó kọ́ wa bí a ṣe le ba ota kookan tí ó bá kọlu wa jagun; bí a ṣe le borí rẹ̀ pẹ̀lú Ọ̀rọ̀ naa, nítorí pé Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ ń bawa gbé osi ń gbé ninú wa. Ó fi dawa lojupé, “AWA NI Ọ̀RỌ̀ NAA”. Nítorí náà ohunkóhun tí a bá béèrè ní Orúkọ Rẹ̀, a le rí i gba bí a bá le gbàgbọ́…. ÀTI PÉ AWA GBÀGBỌ́!

Ó ti sọ̀rọ̀ ó sì ti fihàn wa bí a ṣe le di iri okunrin àti obìnrin pípé kí a lè jẹ́ ibùgbé níbi tí Ó ń gbé. Ó fun ìpè ó sì tún fun ìpè láti kó Ìyàwó re owon jọ láti jẹ́ kí a mọ̀ pé Òun ni atọ́nà wa, ó ń darí osi ń tọ́wa sọ́nà nípasẹ̀ angẹ́lì re tii se atona re lori ilẹ̀ ayé iyen William Marrion Branham.

Ní báyìí Ó ní ẹ̀kọ́ pàtàkì mìíràn tí Ó fẹ́ fi kọ́ wa, kosi fihàn wa. Ó fẹ́ kede wipé a jẹ́ àwọn ọmọ Rẹ̀ ti oti fi sipo omo. Orúkọ wa dára bí Orúkọ Rẹ̀. A ti jáde kúrò ní Kénáànì, kúrò nínú ayé, ní báyìí asi ti wa jókòó pelu re ní ibi giga ninu àwọn ọ̀run, a ń jẹ Mánà

tí ikoko tí a fi pamọ́.
Ní báyìí Ó fe bawa sọ ohun tí a gbọ́dọ̀ ṣe láti múra sílẹ̀ fún Ìwaasu Rẹ̀ tó ń bọ̀, àti ohun tí ó le ṣẹlẹ̀ bí a bá ṣe bẹ́ẹ̀.
A gbọ́dọ̀ ti gbàdúrà daada, ki a sì ti múra sílẹ̀ fún Ìwaasu naa; ki a kó ara wa jọ gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn mímọ́ lati gbọ́ Ohùn Rẹ̀, Olorun yiò báptísi pẹ̀lú Ẹ̀mí Mímọ́, yio fún wa ni àwọn ìbùkún ọ́run; kò sí èrò buburu; kò sí ikunsinu kankan sí ara wa; amaa sọ̀rọ̀ pelu ìfẹ́ àti ìpokanpo; amaa wà ní ìbámu kan, ní isokan ní ìbi giga nunu àwọn ọ̀run lábẹ́ àyíká ọ̀run; gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wa a wa lábẹ́ Ẹ̀jẹ̀ naa, nínú ìjọ́sìn pípé; a o gbe ọwọ́ àti ọkàn wa sókè sí Ọlọ́run, latí maa jọ́sìn papọ̀ ní ìbi giga ninu àwọn ọ̀run.

Bí a bá ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí, èyí ni ohun tó máa ṣẹlẹ̀ ní Ọjọ́ Ìsinmi yìí:

  • Ìwòsàn atọ́run wa,
  • Ìmọ̀tẹ́lẹ̀,
  • Ìsipaya,
  • Àwọn ìran
  • agbara•
  • Awon gbára
  • Àwọn èdè titun,
  • Àwọn ìtúmọ̀ ede,
  • Ọgbọ́n
  • Ìmọ̀
  • Àwọn ìbùkún ọ̀run
  • Ayọ̀ tí a kò le fenu sọ̀, tí ó sì kún fún Ògo

Gbogbo ọkàn ni a maa kun fún Ẹ̀mí mimo. Lẹ́yìn náà lójijì ni iro nla yio ti Ọ̀run wa, Iro kan bí ẹ̀fúùfù lile, Ólorun a sì fi gbígbó ebun emi bùkún fun wa.

Èyí ni ohun tó máa ṣẹlẹ̀ ní Ọjọ́ Ìsinmi yìí ní àago mejila ọ̀sán, àkókò Jeffersonville, níbi tí Ọlọ́run ti pèsè ibi pàtàkì kan níbi tí Ìyàwó le kó ara wọn jọ si láti gbọ́ Ohùn Rẹ̀ pelu okan kan, ní ibi kanna, ti a o si gbe ọwọ́ àti ọkàn wa sókè sí Ọlọ́run, ńi ijọ́sìn papọ̀ labe agbegbe ọ̀run.

Arákùnrin Joseph Branham

Ìwaasu: Ìgbàgbọ́ #1 — 60-0515E

Ese Ìwé Mímọ́: Joeli 2:28
Efesu 1:1-5
I Kọ́ríńtì 12:13
I Pétérù 1:20
Ìfihàn 17:8
Ìfihàn 13