The Seventy Weeks of Daniel Series banner

26-1129 Idi mẹfa ti Gebrieli fi ṣabewo si Daniẹli

BranhamTabernacle.org

Ẹyin eni tí a fẹ́ràn gidigidi,

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan ńlá ló ń ṣẹlẹ̀ tí Olorun si toju pamọ́ fún wa.

Ọlọ́run ń ṣí Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ payá ó sì ń mú un ṣẹ lójoojúmọ́. A ń wádi ìgbà tí a maa gòkè lọ, a sì ń múra sílẹ̀.

A ti gbé ojú wa sí Ọlọ́run nípasẹ̀ àdúrà àti ẹ̀bẹ̀, ó sì ń ṣí wákàtí tí a ń gbé payá fún wa. Àkókò ti tán; Ó ń bọ̀ fún wa, ìyàwó rẹ̀ tí o fẹ́ràn gidigidi.

Ṣùgbọ́n ní àkọ́kọ́, Ọlọ́run kígbe tantan nípasẹ̀ áńgẹ́lì rẹ̀ láti kìlọ̀ fún àwọn ènìyàn Rẹ̀ pé wọ́n gbọ́dọ̀ gbọ́ tirẹ̀. “BÁYÌÍ ni Olúwa wí, Ọlọ́run kò ní bá Ìjọ Rẹ̀ lò títí yóò fi padà sí ilẹ̀ ìbílẹ̀ re, eyi tii se* Ise ìránse wákàtí náà. Ẹ padà sí ìpilẹ̀ṣẹ̀ ojulowo náà!* ”

Mo fẹ́ràn ìyẹn gan-an. Nígbà tí mo bá gbọ́ tí wòlíì kan dìde pẹ̀lú Bayi ni Olúwa Ọlọ́run wí, arákùnrin, ìyẹn ni o, Ni temi o, oro ti buse. Ko ju bee lo.

Ó, eyi wu awa naa gaan. Ó fiwa l’ọkàn bale. A ń ṣe gẹ́gẹ́ bí Ó ti kọ́ wa láti ṣe.

Ní tòótọ́, a kò tíì fi ojulowo Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ sílẹ̀ rí, a ti n dúró pẹ̀lú Ohùn Ọlọ́run lórí àwọn fonran náà nígbà gbogbo, nítorípe Bayi ni Olúwa wí ni!!

A lè má lè lóye gbogbo ohun tí o sọ àti èyí tí a fi n hàn fún wa, ṣùgbọ́n ohun kan tí a mọ̀ ni wipé, a gbà gbogbo Ọ̀rọ̀ tí ó wà lórí àwọn fonran náà gbo.

Ìyẹn ni ọ̀pá ìdiwọ̀n tòótọ́ ní mímọ̀ pé ìwọ ni Ìyàwó Rẹ̀.

Àwa ni egbe àwọn ènìyàn tí wòlíì náà rí lẹ́yìn aṣọ ìkele Àkókò.
Ohùn wa ni ó ń kígbe pé, “A n dúró lórí gbogbo Ọ̀rọ̀ tí o sọ.”

A ń fojusona, a n gbadura a sì ngbe ojú wa soke sí Ọ̀run, a ń retí Bíbọ̀ Rẹ̀.

Gẹ́gẹ́ bí Dáníẹ́lì, Ólorun ti gbọ́ àdúrà wa ó sì ti sọ̀kalẹ̀ láti fi ohun tí Ó ti pinnu fún àwọn Júù àti Jerúsálẹ́mù hàn wa, títí di òpin aye; gbogbo re patapata.

Ó sọ fún Dáníẹ́lì pé, “Pa Àwọn Ọ̀rọ̀ náà mọ́ kí o sì fi èdìdì di Ìwé náà títí di igba ikẹhin.”

Igba ìkẹyìn yẹn ti dé báyìí. Awa na si ti dé. Àwa ni ìyàwó rẹ̀ tí ó fẹ́ràn gidigidi tí ó ti ń dúró dè.

Igba Ìjọ to kẹyìn niyen. Ìse iranse àti ìránṣẹ́ náà jẹ́ ọ̀kan soso, wọ́n sì ń ṣí ohun gbogbo payá.

Ìfihàn tòótọ́ ti Jésù Kristi, tí a ti fi èdìdì dì títí di àkókò yìí, ti wa ni siṣí payá báyìí.

Kì í ṣe Ẹnì kẹta, kì í ṣe Ẹnì kejì, kì í ṣe Ẹnì kẹta, bí kò ṣe Ọlọ́run funrare.

Gbogbo àwọn àṣírí Ọlọ́run wọ̀nyí ni a ó ṣí payá, nítorí a ti kọ ọ́ níbí nínú Ìwé yìí, a ó sì fi hàn fún ìran ìkẹyìn.

Ọlọ́run ń ṣí Oro re payá ju ti ìgbàkígbà rí lọ, ki Ìjọ le ni imurasile fun igbasoke àti láti lọ sílé!!

Ìjọ gbọ́dọ̀ padà sori àwọn fonran. Padà sí ilẹ̀ ìbílẹ̀ re, sí ìbẹ̀rẹ̀. Pada sí Ìse iranse Wákàtí náà, Padà sí Ohùn ojulowo tí ó pè yin. E PADA SI BAYI NI OLUWA WI.

Ni ọjọ Aiku yii, sọ fun pastọ rẹ pe, “Ẹ jẹ ki a gbọ Ohùn ojulowo ti Ọlọrun loni. Ohùn ti Ọlọrun yan lati fi sọrọ fun ara Rẹ.

Ohùn ti yoo ṣafihan wa si Oluwa Jesu nigbati O ba de. Ohùn kanṣoṣo ti Ọlọrun funrarẹ sọ pe, Emi ni Ohùn Ọlọrun si yin.”

Ko le si Ohùn ti o tobi ju Ohùn yẹn lọ. Ohùn kan ti gbogbo wa le sọ AMIN si gbogbo Ọrọ re.

Ẹ kaabo lati darapọ mọ ara Iyawo kakiri agbaye bi Ọlọrun ṣe n sọrọ ti osi n ṣafihan akoko wiwa re gangan. Yoo jẹ ami ororo ti o tobi julọ ti e ti gbọ ri.

A ma pejọ ni agogo mejila osan, akoko Jeffersonville, lati gbọ: 61-0730E – “Idi mẹfa ti Gebrieli fi ṣabewo si Daniẹli”

Arakunrin Joseph Branham