Eyin atunbí owon,
Nípa títẹ Play, a ń gbọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí kò lee ye. Ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan jẹ́ Òtítọ́, ni gbogbo gbolohun Rẹ̀. A pe wa, a sì pa wa mọ́, a kún wa, a sì yà wá sọ́tọ̀; a kún wa pẹ̀lú Ẹ̀mí Mímọ́, a sì ti wà ní Ilẹ̀ Kénáàni báyìí. A kò bẹ̀rù ohunkóhun…KÒ SÍ NKANKAN, a mọ ẹni tí a jẹ́.
Nítorí pé a dúró pẹ̀lú Ọ̀rọ̀ Rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Ó ṣe pàṣẹ fún wa láti ṣe, Ó ń bọ̀ wá sọ fún wa pé Ó fi ogún sílẹ̀ fún wa.
Nígbà wo ni Ìwọ ṣe bẹ́ẹ̀, Baba? Nígbà tí Mo yàn yín ti Mo sì fi orúkọ yín sínu Ìwé Ìyè Ọ̀dọ́-Àgùntàn ṣáájú ìpìlẹ̀ ayé ni.
Nígbà tí ekúnrere akoko dé, Mo rán Jésù Ọ̀dọ́-Àgùntàn naa, Ẹni tí a pa láti ìpìlẹ̀se ayé, kí ẹ lè gba ogún yín láti jẹ́ àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin Mi, àwọn olorun kékekée.
Mo ní láti ṣàyẹ̀wò yín fún àwọn ìbi ton pariwo àti àwọn ibi tó ko le dada ṣáájú kí n lè fiyín sipo omo.
• “Ṣé o gbàgbọ́ pé sise atunte Ohùn Mi lórí àwọn fonran nínú ijo jẹ́ ohun búburú?”•
“Bẹ́ẹ̀ni, kò yẹ kí e te teepu nínú ijo• “Dá a lẹ́jọ́ toba fe. Aye yen n pariwo.”
• “Ṣé o gbàgbọ́ pé Ọ̀rọ̀ Mi lórí àwọn teepu nílò ìtumọ̀?”• “Bẹ́ẹ̀ni, Ó nílò ẹnìkan láti ṣàlàyé Rẹ̀.”•
“Aye yen npariwo. Lé e jáde. O kò tíì ṣe tán.”
Nígbà tí o bá ṣe tán, o maa se “Amin” sí Ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan.
• “Ṣé o gbàgbọ́ pé Èmi ni okan náà lánàá, lónìí àti titi láéláé?”• “Amin.”• “Ṣé o gbàgbọ́ pé Ohùn Mi lórí àwọn teepu ni OHÙN TÓ ṢE PÀTÀKÌ JÙ LỌ tí o gbọ́dọ̀ maa gbọ́ ni?”•
“Amin.”• “Ṣé o gbàgbọ́ pé Ohùn Mi lórí fonran yóò so Iyawo náà pọ̀?”• “Amin.”• “Ṣé o gbàgbọ́ pé àngẹ́lì Mi alágbára yóò ṣàfihàn rẹ sí yin?”• “Amin.”
Okun Ife ti afi di o ti nle báyìí. Mo ti ṣàyẹ̀wò rẹ fún àwọn ìró ariwo àti àwọn ibi tó de. Mo ti ṣe tán láti tilẹ̀kùn. N ó fi Èdìdì Mi di o. O ti yege ninu àyẹ̀wò Mi.
Nísinsìnyí jẹ́ kí N sọ nǹkan kan fún yín, eyan ènìyàn Mi, olùfẹ́ mi owon ní ilẹ̀ ti eti n gbó awon fonran woli; ní òkè òkun àti níbi gbogbo tí ẹ ba wà, ẹ má bẹ̀rù.
Ko sewu. Mo ti mọ̀ yín ṣáájú ìpìlẹ̀se ayé. Mo mọ ohun gbogbo tí yóò ṣẹlẹ̀.
Mo ń bọ̀ wa mu yín láìpẹ́, N ó sì mú yín lọ sí Ibìkan tí kò sí ikú, kò sí ìbànújẹ́, kò sí owú jije, kò sí ǹkankan miran; àfi pípé, ìfẹ́ pípé.
Títí di ìgbà náà, ẹ máṣe gbàgbé eyi, Mo ti fún yín ní Ọ̀rọ̀ Mi, ẹ̀yin NI Ọ̀RỌ̀ MI tí a ṣo di ara. Bí ẹ bá nílò NǸKAN KANKAN, ẹ sọ Ọ́, ki ẹ si gbàagbọ́; Ogún yín ni.
N ó tun rán Ohùn Mi sí yín lẹ́ẹ̀kan síi ní Ọjọ́ Àìkú yìí, N ó sì ṣàlàyé gbogbo re fún yín. N ó sọ fún yín lẹ́ẹ̀kan síi iru ẹni tí ẹ jẹ́, ibi tí ẹ ń lọ, àti bí oun ṣe rí, lowolowo yi.
Ẹ wá darapọ̀ mọ́ awon Iyawo Mi gẹ́gẹ́ bí n o ṣe ń jẹ́ kí wọn jókòó papọ̀ nínu ìbi giga ninu àwọn ọ̀run ní Ọjọ́ Àìkú yìí ní agogo 12:00 ọ̀sán, àkókò Jeffersonville, kí ẹ sì gbọ́ bí Mo ṣe ń gbé yín sí ipò nípa Ọ̀rọ̀ Mi. 60-0522E Adoption #4
Arákùnrin Joseph Branham