26-1108 Ìgbàgbọ́ #3

Ẹyin omo to ati fi sipo omo o,

Àwọn ìjọba ayé ń sọ fún àwọn ènìyàn pé, “Ẹ múra sílẹ̀, ẹ ṣe tán fún ọjọ́ ìbi. Ẹ kó oúnjẹ àti omi pamo fún ìdílé yín kí ẹ lè múra sílẹ̀ fún ohun tí ń bọ̀ wa sele.”

Ayé wà nínú ìbẹ̀rù. Won nbere pe kí ni yóò ṣẹlẹ̀? Kí ni ọ̀la yóò mú wá?

A ń rí bi àsọtẹ́lẹ̀ se ń ṣẹ ni ojú wa. Ayé ń wó lulẹ̀. Ìbẹ̀rù àti ẹ̀rù ń tàn káàkiri ayé, a kò mọ̀ ohun to fee sele. Kí ni mbo wa sele lọjọ́ iwájú? Kí ni a lè ṣe? Ṣé òpin ti de ni?

Esi wa wo o, Ọlọ́run Baba wa ti ń kìlọ̀ fún wa, Ó sì ti ń múra wa sílẹ̀. Ó ti kó oúnjẹ àti omi wa pamo, a sì ti ń jẹ, a sì ń mu láti inú kànga agboigbe wa. A ti ṣe tán, kìí ṣe fún ọjọ́ ìparun, ṣùgbọ́n fún Ìgbasoke awa ayanfe!!

Ìyàwó Kristi kò tíì ní ayọ̀ tàbí ìtẹ́lọ́rùn ju èyí lọ rí.

Ọlọ́run Baba wa ń sọ fún Ìyàwó Rẹ̀ pereté káàkiri agbayé pé, “Ẹ Má Bẹ̀rù, ẹ maa yọ̀. Ẹ jẹ́ Àwọn Tí Mo ti Yàn. Mo ń múra yín sílẹ̀ fún Ìgbasoke, Ọjọ́ Ìgbéyàwó yín. Mo ń mú yín kúrò nínú rúdurùdu aye yìí.

Ẹ jẹ́ Àwọn Ọmọkùnrin àti Ọmọbìnrin mi Tí Mo ti fi sipo omo. Ekunrere akókò ń bọ̀.”

Ayo idasile ńlá ni a ní. Ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan tí a n gbọ́ jẹ́ ese wúrà fún wa. A máa mú Un, a sì máa ń ṣe e lóṣó latigba degba.

Lẹ́yìn náà a máa sọ pé:
“Mímọ́, mímọ́, mímọ́, sí Olúwa.” “Mímọ́, mímọ́, mímọ́, sí Olúwa.” “Mímọ́, mímọ́, mímọ́, sí Olúwa.”
A n gbe ojú wa wà soke sí Kálfárì, kò sí ohun kan tí yóò dá wa dúró! A ń rìn lójú ọ̀nà Ọba, a n ta òróró ìyàsímímọ́ iyebiye le wa lori, a ń wọ inú Ibi Mímọ́ jùlọ.

Nígbà tí ọ̀tá bá gbìyànjú láti sọ fún wa pé a ti sọnù, pé a kìí ṣe Ìyàwó Kristi, a kàn maa Tẹ Play ni, Ó sì ń kígbe sí wa pé:

Ẹ yọ èyí kúrò nínú ọkàn yín pé ẹ ó sọnù, pé ẹ ó ṣe èyí, pé ẹ ń bẹ̀rù èyí.

Ẹ má ṣe bẹ̀rù ohunkóhun, nítorí ó ń gbìyànjú láti sọ fún yín ibi tí ẹ wà, ẹni tí ẹ jẹ́, bíí tí ẹ ṣe dúró.

Ayé wà nínú ÌBẸ̀RÙ, bee náà ni Ọlọ́run Baba wa ń sọ fún wa pé, “Ẹ má ṣe bẹ̀rù OHUNKÓHUN, Mo ń sọ fún yín ẹni tí ẹ jẹ́ àti ibi tí ẹ ń lọ.” …ÒGO NI F’OLORUN!!

Nínú àìlera wa gẹ́gẹ́ bí ènìyàn, a máa ń ṣubú lójoojúmọ́. A máa ń ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àṣìṣe. A máa ń ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun tí kò yẹ kaṣe. Lẹ́yìn náà èṣù a máa lu wa, a máa lu wa, ó ń sọ pé báwo ni a ṣe lè jẹ́ Ìyàwó Kristi.

Ṣùgbọ́n a ti fi oro Olorun ko wa. A mọ ohun tí a ó se gaan:
Tẹ Play láti gbọ́ ohun tí Olorun Bàbá wa ń sọ.

Nísìnyí, ẹ lè ṣe ohun tí kò tọ́, nígbàkúgbà tí ẹ bá ṣe ohun tí kò tọ́, ẹ ó jiya rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni, sa, ẹ ó ká ohun tí ẹ gbin! Ṣùgbọ́n èyí kò ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú ìgbàlà yín.

Nígbà tí a ba bí yín nípasẹ̀ Ẹ̀mí Ọlọ́run, ẹ ní Ìyè Àìnípẹ̀kun, ẹ kò sì lè kú ju níwon igbà ti Ọlọ́run ko lè kú. Ẹ jẹ́ ará Ọlọ́run, ẹ jẹ́ ọmọ Ọlọ́run.

Ó tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn láti yàn wá tẹ́lẹ̀. Ó tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn láti ṣe wá ní Ọmọkùnrin àti Ọmọbìnrin re.

Ó tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn láti Gbàwá wọlé. Ó tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn láti fún wa ní Ìfihàn tòótọ́ nípa ẹni tí Òun jẹ́ àti ẹni tí àwa jẹ́. Ó tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn láti mú ángẹ́lì Rẹ̀ kọjá aṣọ ìkele àkókò kí ó sì fii hàn wa ní iha kejì nibi yi kí a lè yọ̀, kí a sì MÁ BẸ̀RÙ.

Ó ṣeni láànú pé àwọn fonran wọ̀nyí kìí ṣe fún gbogbo ènìyàn. Wọ́n jẹ́ ti ìjọ wòlíì nìkan…

Ògo ni fun Olorun, àwa niyen. Ní gbogbo ìṣẹ́jú tí a bá lè see, àti nígbàkúgbà tí a bá pejọpọ̀, ohun tí a fẹ́ nìkan ni láti Tẹ Play láti gbọ́ Ohùn Ọlọ́run.

Óti ye awọn kan dáada. Wọn kò i ti rí i bí àwa ṣe rí i. Won saa loye re, ṣùgbọ́n fún àwa… Ó dára láti wo ó; nítorí a mọ̀ pé Òun ni ọ̀nà tí Ọlọ́run baba wa ti pèsè fun wa lòní ni.

Lójoojúmọ́ ni awon arayé àti àwọn ènìyàn rẹ̀ ń ní ìnira sí i. Ohun gbogbo ń ṣókùnkùn sí i, ó sì ń di baibai. Ṣùgbọ́n fún Ìyàwó Kristi, ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ń mú ìtùnú wá nípasẹ̀ Ìfihàn.

A wà ní ìsinmi, a ti kún wa fún Ẹ̀mí Mímọ́ Rẹ̀, a jókòó papọ̀ ní àwọn ibi giga ninu àwon ọ̀run.

Ǹjẹ́ ẹ ti rònu rí pé báwo ni ó ṣe rí ní ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́stì nígbà tí iro nla bi ti ẹ̀fúùfù líle dé, ti Ẹ̀mí Mímọ́ sì kún yàrá náà, àti gbogbo awon tí ó wà níbẹ̀?

Ẹ má ṣe ròo mọ́. Ẹ wá dara pọ̀ mọ́ wa ní ọjọ́ Sunday ní agogo méjìlá ọ̀sán, àkókò Jeffersonville, bí Olorun yio ṣe ko àwọn idì Rẹ̀ jọ, ti yio kún yàrá yín pẹ̀lú Ẹ̀mí Mímọ́ Rẹ̀,

Ó sì ń múra wa sílẹ̀ fún Ìpadàbọ̀ Rẹ̀ tí ó sún mọ́ tòsí nípa fífún wa ní oúnjẹ tí Ó ti kó pamo. Ẹ maa jẹ, ẹ ó sì mu láti inú ilé ìṣúra Rẹ̀, Ohùn Ọlọ́run lórí fo’ran.

Latí odo Arákùnrin Joseph Branham

Ìwaasu: Fifi Omo sipo #3 60-0522M

Àwọn Ẹsẹ Ìwé Mímọ́:
Mátíù 28:19
Jòhánù 17:7-19 Ìṣe Àwọn Àpọ́sítélì 9:1-6, Orí 18 àti 19
Iwé Ròmù 8:14-19
1 Kọ́ríńtì 12:12-13
Gálátíà 1:8-18
Éfésù Orí 1 Hébérù 6:4-6, 9:11-12

BranhamTabernacle.org