26-1101 Ìgbàgbọ́ #2

Eyin Olufe ọ̀wọ́n,

Ṣé e ti ṣetán? Awọn ọmọkùnrin àti awon ọmọbìnrin Ọlọ́run tí a ti fi hàn, tí a sì ti fi sipo omo, láti jókòó papọ̀ ní ìbi giga ninu àwọn ọ̀run, tí a so pọ̀ mọ́ Ìyàwó láti gbogbo ayé, láti gbọ́ ohùn Ọlọ́run tí ó ń bá yin sọ̀rọ̀ latẹnu si etí?

Bẹ́ẹ̀ni!!! A ti ṣetán láti gbọ́ ohùn Ọlọ́run tí ó ń sọ ẹni tí a jẹ́ ni pato fun wa.

Mo pè yin ní “olufe” nítorí pé be le je. Eyin,— eyin ni àwọn olufe mi. Ṣé e mọ̀? E jẹ́ kí…a wo ese iwé Mímọ́ kan. Pọ́ọ̀lù sọ pé, “Mo ń jowú lórí yín (Ìjọ Rẹ̀) pẹ̀lú owú iwabi Ọlọ́run, nítorí mo ti fẹ́ yin sona.” Se oye yin? Bose ri gaan niyen. Bẹ́ẹ̀ ni. “Nítorí mo ti fẹ́ yin sona, mo ti fẹ́ yin sona fun Kristi, gẹ́gẹ́ bí wúńdíá tiko labawon.”

Ògo ni fún Ọlọ́run, áńgẹ́lì Rẹ̀ ti fẹ́ wa sona fún Un. A jẹ́ wúńdíá ti ko labawon fun Ọ̀rọ̀ Rẹ̀, Ìse iranse yìí, Ohùn Rẹ̀ lórí àwọn fonran. A ti fẹ́ wa sona fun Kristi nísinsìnyí.

A ó mura sile pelu ìfojúsùn ńlá ní ọjọ́ Àìkú. A o ge ìka wa jẹ, a ó fi ọwọ́ lu oọkàn aya wa, a ó sì ja ọkàn wa leekanna. A ó tún máa kígbe lẹ́ẹ̀kan sí i, a ó máa yin Olúwa, a ó máa kígbe “àmín, hallelujah”, gẹ́gẹ́ bí ìgbà tí àwọn ìràwọ̀ òwúrọ̀ kọrin papọ̀ tí àwọn ọmọ Ọlọ́run sì ń hó fún ayọ̀; nígbà tí wọ́n rí ètò ìgbàlà, nígbà tí Ọlọ́run fi orúkọ wa sínu ìwé Rẹ̀ saaju ìpìlẹ̀se ayé.

Ǹjẹ́ a lè lóye pé Ọlọ́run wa, baba wa, ti dúró de wa, láti ìpilese ayé, títí di òní yìí? Ó rí ibi tí a ó ti farahàn ní igba ìkẹyìn yi, ó sì ti ń dúró, ó sì ń kérora fún wa láti dìde pẹ̀lú agbára Ẹ̀mí Mímọ́ láti fi àwọn ohun ìkọ̀kọ̀ tí a ti fi pamọ́ di Oni yi hàn wá.

Láti iran diran, ni àwọn wòlíì ti dúró títí di ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí kí Olorun le fi àwọn nǹkan wọ̀nyí hàn. Baba wa, Ọlọ́run wa sọ pé òun ti dúró de Ìjọ Rẹ̀ láti dagbà, latí ìgbà Ijo Luther, ìgbà ijo Baptist, ìgbà ijo Methodist, ìgbà ijo awon afedefo, àti nísinsìnyí títí dé ibi tí a ó ti fi òkúta asibòrí náà lélẹ̀. Nígbà náà ni Ilé kiko náà yio parí.

awon ojọ́ tí Olúwa ti seleri tí ó sì ń fẹ́ ko wàye ń ṣẹlẹ̀ nísinsìnyí tí a sì ń mú ṣẹ níwájú wa… ÀTI NÍNÚ WA. A wà nínú Kristi Jesu nísinsìnyí, a n jókòó nínu àlàáfíà atọ̀runwa, ìbùkún ọ̀run, Ẹ̀mí ọ̀run, níbi tí ohun gbogbo ti jẹ́ tiwa. A wà ní Ilẹ̀ ìlérí asi n jogun ohun gbogbo.
Irú ọmọ rẹ̀ àkọ́kọ́ ti gbo, a sì fi i sókè níwájú Ìyàwó Rẹ̀. Ẹ̀mí Mímọ́ n jise padà fun Olorun Baba wa, ó sì n sọ èyí nípa áńgẹ́lì alágbára Rẹ̀:

Angẹli yin ń dàgbàsókè nínu oore-ọ̀fẹ́! Ó ń la papa oko tutu koja. Ó ń ko awọn àgùntàn re, ó sì lè tọ́jú wọn gẹ́gẹ́ bí ìwọ ṣe ń ṣe. Kò ní fún wọn ní epo je láéláé. Kò ní fún wọn ní dagunro je láéláé. Nígbà tí wọ́n bá wa, tí wọ́n ń wí pé, ‘Awa fẹ́ dara pọ̀ mọ́ ìjọ,’ yió wí fun won pé, ‘Ẹ pa ẹnu yín mọ́, ẹ kò nílò ìyẹn! Rárá sa. Èyí ni ohun tí ẹ nílò, “Ẹ ronú pìwàdà kí a sì bamitíìsì, olúkúlùkù yín, ní Orúkọ Jésù Kristi, fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ yín. Ẹyin ó si gba ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́.”’

“Ó! nje Olorun sọ bẹ́ẹ̀ ní tòótọ́ bí?”

“Bẹ́ẹ̀ni, sir, ó dájú pé ó ṣo bẹ́ẹ̀.”

“Ó dára, bẹ́ẹ̀ ni mo ṣe kọwe re.”

“Bẹ́ẹ̀ gan lóṣe sọ ọ́.”

“Nje e mọ̀? Mo rí lagbaja tii se Bíṣọ́ọ̀bù Àgbà, o sọ fún un wipé ‘kò lè wá sí ìlú yìí láti ṣe ìpàdé ita gbangba’ Ṣùgbọ́n, se e mọ̀, emi Olorun nimo darí rẹ̀, mo wípe, ‘Iwo saa lọ labe isakoso bó ti wù kí ó rí.’ Wọ́n sọ fún un pé ó yẹ kí ó pale gbogbo àwọn fonran rẹ̀ mo, ko má sì se jẹ́ kí wọ́n jáde. A saa lọ labe isakoso bó ti wù kí ó rí!”

“Ọmọ tí mo fi sipo omo ni mo ti ń retí. Nísinsìnyí mo lè sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ rẹ̀ kí n sì sí gbogbo àṣírí ìkọ̀kọ̀ mi payá fún àwọn àgùntàn mi.”

“Ọlọ́run wa Bàbá wa Àgbàyanu nio”

“Ṣé o fẹ́ kí n ròyìn fún ọ nípa àwọn ọmọ rẹ yòókù?”

“Bẹ́ẹ̀ ni, báwo ni wọ́n ṣe ń ṣe?”

“Óò Bàbá…Ìwọ́ yóò máa fi wọn yangan. Wọ́n jo Baba to biwon. Àwọn bíṣọ́ọ̀bù àgbà àtijọ́ náà ṣì ń sọ ohun kan náà fún wọn, kí wọ́n má lọ sí àwọn ilé ìjọsìn ohun wolii ti a ka sile, láti gbọ́ ohùn rẹ. Wọ́n sọ pé àwọn fonran náà ko lo se pàtàkì jùlọ tí wọ́n gbọ́dọ̀ maa gbọ́; àwọn ohùn miran to se pàtàkì jù bẹ́ẹ̀ lọ wà nísinsìnyí.”

“Nje o mọ ohun tí àwọn àgùntàn rẹ sọ fún wọn àwọn oníwàásù wonyen?”

“Epá ẹnu yin mo, Awa n duro ti àwọn fonran náà, awa n dúró ti ohùn Ọlọ́run.”

“Ṣé wọ́n see lóòótọ́ looto?”

“Bẹ́ẹ̀ ni, sa, wọ́n dà bí ìwọ náà.”
“Ó dára gan-an. Èyí fún mi láyọ̀ gan-an ni. Mo ti ń reti wọ́n tipe típẹ́. Nísinsìnyí àwọn náà ti ṣetán fún ìfọmọsipo!!”
“Wọn yóò wà lenu iṣẹ́ wọn ní ọjọ́ Àìkú yìí ní agogo 12:00 òsan, àkókò Jeffersonville, láti gbọ́ ohùn rẹ. Wọn yóò wà ní ìṣọ̀kan, wọn yóò sì kóra jọ láti gbogbo àgbáyé, wọn yóò sì pe gbogbo ènìyàn láti dara pọ̀ mọ́ wọn.”

“Ó dára, Èmi yóò wà níbẹ̀ pẹ̀lú wọn.”

Arákùnrin. Joseph Branham

Ìránnilétí: Emá ṣe gbàgbé nípa Àkókò Ìpamọ́ Ọ̀sán

Ìwaasu ti a o gbo: Ìfomo sipo #2 60-0518

Ese iwé Mímọ́:
Jẹ́nẹ́sísì 1:26
Éfésù ori kini
Róòmù 8:19
Gálátíà 1:6-9
Hébérù Orí Kẹfà
Jòhánù 1:17