26-0712 Ìfihàn ti Jésù Kristi

Eyin egbe awon omo woli owọn,

Èwo bi ati feran oro naá to. IFIHAN…Akole so asoju bi gbogbo ifihan otito nipase emi mimo se je pataki to fun onigbagbo otito. Ifihan see pataki ju iye lo fun aya Kristi. Nitori Jesu wipe ..”LORI APATA YI, tii se IFIHAN, ni emi yio ko ijo mi le, ati nipa oore ofe ati aanu Ólorun, awa ni ijo re ton duro lori ifihan otito re.

Iwe ifihan kii se fun gbogbo enìyàn. Kosi eniti ole loye re. Iwe asolete woli ti a ko fun egbe awon Omo woli ni. Awọn nikan losi le loye re. Awa nio, awa iyawo Jesu Kristi ni.

Iwe ifihan je iwe kan ti Kristi ko funrare ninu gbogbo Bibeli. Sugbon o ran angeli re lati fi han Johanu iranse re. Awon omo ehin re ko loye awon otito ti a ko sile wonyi. Akoiti fi han won saaju Akoko naa. Jesu paapa kole salaye aye tire funwon nibe, nitori wipe Baba re koiti fi haan.
Ṣùgbọ́n nísinsìnyí, lẹ́yìn ikú àti àjíǹde Rẹ̀, àti ní lowolowo yìí, Ó lè ṣàlàyé Ìfihàn Ara Rẹ̀ yìí fún Jòhánù, ohun tí ògo Rẹ̀ àti wíwà laayè Rẹ̀ yio se nínú ìjọ.

Ṣùgbọ́n nísinsìnyí, lẹ́yìn ẹgbẹ̀rún ọdún méjì, ayé ti ronú jinlẹ̀, àwọn onímọ̀ eko bibeli ti kẹ́kọ̀ọ́ wonsi nfori kori, ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó ní ìtumọ̀ àti Ìfihàn tóotọ́ nipa àwọn ohun ìjìnlẹ̀ wọ̀nyí tí a kọ sínú Ìwé Ìfihàn títí di òní yìí, títí di àkókò yìí, nígbà tí Ọlọ́run rán áńgẹ́lì kan náà sí ayé láti fi gbogbo Rẹ̀ hàn fún wa, Ìyàwó Rẹ̀ tí Ó yàn.

Bi a ba gbìyànjú láti lóye ohun nla nipa bí Ọlọ́run ṣe yàn mí, tí Ó sì yàn ọ́; láti ní Ìfihàn Òtítọ́ ti Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ kọjá ohun ti ale fi s’apejuwe.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ènìyàn ló sọ pé wọ́n ń tẹ̀lé Ìse iranse yi, tí wọ́n sì nsọ wipé wọ́n gbàgbọ́ pé Ọlọ́run rán wòlíì kan, wọn kò ní ekunrere Ìfihàn lati mo ijiya àìsọ Ohùn Rẹ̀ di ohùn pàtàkì jùlọ tí wọ́n gbọ́dọ̀ maa gbọ́. Níní Ìfihàn Ohùn Rẹ̀ yìí ní ọjọ́ yìí jẹ́ isura iyebíye gidi.

Ọlọ́run ti yàn wá láti fí Ìfihàn Òtítọ́ yẹn han wa. Nítorí náà, àwa ni ìjọ rẹ̀ tòótọ́, ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ tí a kò lè ṣẹ́gun, tí Sátánì kò lágbára niwaju re, tí a sì ti ba agbara re je. Pẹ̀lú ìfihàn tòótọ́ rẹ̀ nínú ìgbésí ayé wa, ẹnu ọ̀nà ọ̀run àpáàdì kò lè borí wa, ṣùgbọ́n àwa ni yóò borí wọn. Kò sí ohun tí ó lè dúró níwájú wa.

Ekunrere Ìfihàn tòótọ́ fún ojo òní ni láti mọ pàtàkì ohùn Ọlọ́run fún ọjọ́ wa. Tí lílọ sí ṣọ́ọ̀ṣì, jíjẹ́ omo ìjọ, fifi arawa rubọ, gbígbàdúrà, àti ijọ́sìn si Ọlọ́run bá jẹ́ ohun tí Ọlọ́run ń béèrè niyen, nígbà náà Ọlọ́run yóò jẹ́ aláìṣòdodo láti dá Kainì lẹ́bi fún aíṣe ohun tí Ó sọ pé kí ó ṣe gan-an.

Èyí ni ìtumọ̀ ohun tí Ohùn woli lórí àwọn fonran náà túmọ̀ sí fún wa:

Ìfihàn gbogbo ohun tí a gbé kalẹ̀ níbí pẹ̀lú ìbùkún fún ẹni tí ó nkà á tí ó sì ngbọ́ ọ, pẹ̀lú ègún fún awọn tí yóò fi kún tàbí yo kúrò nínu re. Ó jẹ́ ìwé àkójọpọ̀ pípé, ah, ani paripátápátá ni. Kò sí ohun tí a lè fi kún un. Nígbà tí ènìyàn bá gbìyànjú láti yo ohunkóhun kúrò nínú Rẹ̀, tàbí láti fi ohunkóhun kún un, Ọlọ́run sọ pé Òun yóò yo ipá tire kúrò nínú Ìwé Ìyè. Se e rii? Ó máa yo ipa tirẹ̀ kuro ninú Ìwé náà, bí ó bá fi kún un.

Kò tíì sí ìgbà kan rí, ti Ọlọ́run ti pèsè ọ̀nà pípé láti má ṣe fi kún tàbí yo kúrò nínú Ọ̀rọ̀ Rẹ̀. Ó ti fún wa ní àǹfààní láti maa gbọ́ ohùn Rẹ̀ bí Ó ṣe ń sọ̀rọ̀ ti osi nfi Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ hàn wá. Ni kukuru, kò sí ohun tó ju eyi lọ.

Èyí ni ÌṢÍPAYA TÒÓTỌ́ fún ojo òní.

Inu mi dun gidigidi mosi wa ni ìfojúsùn ńlá fún gbogbo ohun tí Olúwa ní ní ìpamọ́ fún wa bí a ṣe ń fetísílẹ̀, ti a nkà, ti asi nkẹ́kọ̀ọ́ nípa Igba ìjo Méje. Ọlọ́run lo kọ ọ́, ó si fi rán áńgẹ́lì Rẹ̀ láti fi hàn Jòhánù, lẹ́yìn náà ó dúró dè wá láti wà níbí lórí ilẹ̀ ayé ní àkókò yìí gan-an kí Ó lè rán áńgẹ́lì kan náà sí wa láti fi hàn wá!

Kò tíì sí àkókò ti o lógo julo bi t’ojo òní nínú ìtàn ayé. Kò tíì sí ọlá nla tí a fi fún ènìyàn ju láti ní àǹfààní láti gbọ́ ohùn Ọlọ́run fún ara wọn lọ. Kò tíì sí àkókò kan rí tí a lè so ìyàwó Rẹ̀ pọ̀ nípasẹ̀ Ohùn Rẹ̀ ní àkókò kan náà.

Múra sílẹ̀, Ọlọ́run yóò fún wa ní ìfihàn ara rẹ̀ sí i làti mo ẹni tí a jẹ́: Ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ tí a kò lè ṣẹ́gun, ìyáàfin rẹ̀ tí o ti yàn, olólùfẹ́ rẹ̀ tí ó ti ń dúró dè láti ìbẹ̀rẹ̀ ayé.

Kò sí ohun tí ó lè gba èyí lọ́wọ́ wa. Ó dúró sinsin sínú ọkàn àti oọkàn aya wa ju ti tẹ́lẹ̀ lo. Ó ti di òótọ́ tí ó ń fún wa ní ìgbagbọ́ ìgbàsoke báyìí.

A ó bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò wa ńlá yi ní ọjọ́ Àìkú yìí ní agogo mejila òsan, àkókò Jeffersonville, bí a ṣe ń gbọ́ Ìwaasu akọ́kọ́ ti woli pe ni: Ìfihàn ti Jésù Kristi 60-1204M.

Mo fẹ́ gbà ọ́ níyànjú láti gbe ìwé Igba ìjo meje tirẹ, ka á nínu yara re pelu idákẹ́ jẹ́ẹ́ kí o sì kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, ni orí kookan, ní ọ̀sẹ̀ kọ̀ọ̀kan. A ó para pọ̀ láti gbọ́ ohùn Rẹ̀, lẹ́yìn náà kí a kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Rẹ̀.

Arákùnrin Joseph Branham