26-0705 Édẹ́nì ti Sátánì

Ìyàwó Pípé Ọ̀wọ́n,

Ṣùgbọ́n láti rí ẹ̀tàn ọ̀tá, kò tíì sí ọjọ́ kan bí èyí tí a ń gbé ninu re báyìí rí. Ọjọ́ ẹ̀tàn àti ẹ̀tàn to ga jùlọ ni. Nígbà tí mo bá sì rí èyí, ó mú èyí wá, pé, Kristẹni gbọ́dọ̀ wà ní Oju l’alakan Fi nsori lónìí ju bí ó ti rí ní gbogbo awon iran isaju lo.

Arákùnrin Branham sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún Ìyàwó ní nǹkan bí ọdún mokanlelogota (61 years) sẹ́yìn títí di òní. Báwo ni ẹ̀tàn ọ̀tá ṣe rí ní ọdún mokanlelogota sẹ́yìn sí ìsinsìnyí? Láti fi ojú ìwòye mìíràn wo, bawo, ni ìmọ̀ ẹ̀rọ ayé se ri ní ọdún mokanlelogota sẹ́yìn ní ìfiwéra pẹ̀lú ohun tí ó jẹ́ lónìí?

Ọdún 1961 ni ìbẹ̀rẹ̀ eré-ìje imo sayensi lo sinu ofurufu Awọn ero kọ̀ǹpútà ńla gbangba bi ero amohumaworan. Awọn nkan bi káàdì ‘ní ó nlò àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì to kose mose lo le loo. . A maa nso àwọn tẹlifóònù mọ́ ògiri ni, waya ni o nlo, alafowoyi si ni. Beena ni ero Redio, ero itewe alafowotemole, ati ero isiro owo oni batiri.

Ṣùgbọ́n lónìí a ní ero ayelujara (Íńtánẹ́ẹ̀tì), àwọn ètò ọgbọ́n àtọwọ́dá tí ó lè ṣẹ̀dá iṣẹ́ ọnà, iwe kiko, àti ṣíṣe ìrànlọ́wọ́ pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ lai f’àkókò jafara. Àwọn rọ́kẹ́ẹ̀tì ara tí won fi ń lọ sí Mars. Àwọn fóònù alágbéká tí kó tóbi, àwọn aago ọlọ́gbọ́n, àti àwọn ẹ̀rọ ara ẹni tí àwọn ero alatagba aláìlókùn àgbáyé ń ṣiṣẹ́ tí wọ́n ń so àwọn ènìyàn bílíọ̀nù pọ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ nípasẹ̀ ohùn, atejise, àti fídíò. Àwọn ero olùrànlọ́wọ́ ti a mosi robot.

Àrékérekè àti ẹ̀tàn ọ̀tá ni iran yi tayo t’awon iran ti o ti kòja lo. Irúgbìn búburú ti Sátánì ti dàgbà o si ti gbo, ó sì ti ṣẹ̀dá Édẹ́nì ti Sátánì. Ṣùgbọ́n ní àkókò kan náà, Ọlọ́run ní Ìyàwó kan tí ó ti dàgbà ti o si ti gbo. Irú Ọmọ Ọba naa tí ó ti múra sílẹ̀ nípa jíjókòó níwájú Ọmọ Rẹ̀, Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ ati Ohùn Rẹ̀.

Ọlọ́run mọ̀ pé Ó ní láti pèsè ọ̀nà láti maa bo Ìyàwó Rẹ̀ ní àkókò ẹ̀tàn àti iran búburú yìí. Ọ̀nà pípé tí wọn kò ní ní láti was nì ailoye, láti maa se eyi je, eyi ò je tàbí láti fi ọ̀rọ̀ ẹnikẹ́ni ropo Ọ̀rọ̀ Olorun tòótọ́ tí kò ní àbùla. Ó mọ̀ pé wọn yóò nílò láti gbọ́ Ohùn Ọlọ́run fún ara wọn, nítorí Ó kìlọ̀ fún wa pé yóò sún jo arawon débi pé yóò tan àwọn Àyànfẹ́ náà jẹ bí ó bá ṣeé ṣe.

Àwọn ènìyàn lè jẹ́ ẹni àmì òróró, kí wọ́n kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, kí wọ́n sì jẹ́ èké. Ólorun ní láti pèsè ọ̀nà kan. Nítorí náà, Ó ṣe Ọ̀nà Pípé fún Ìyàwó Rẹ̀, èyí tí yóò dàbí ohun tí kò ṣeé ṣe nígbà tí Ó bẹ̀rẹ̀ sí ní gba ohùn Rẹ̀ sílẹ̀ ní ọdún 1947; pé nípa fífi ìka wọn tee mole, ayé lè fi eti arawon gbo gbogbo Ọ̀rọ̀ tí Ó bá sọ, koda ní èdè tiwọn. Kò ní sí ìbéèrè, kò si ni si ìyàlẹ́nu. Wọ́n lè fún ara wọn gbo bayi ni Oluwa wi.

Ó tilẹ̀ ti la ọ̀nà kan tí Ó lè fi so Ìyàwó Rẹ̀ pọ̀ kárí ayé láti gbọ́ Ohùn Rẹ̀, ní àkókò kan náà, kí wọ́n lè wà ní ọkàn kan, ní ìṣọ̀kan, kí wọ́n gbọ́ Ọ̀rọ̀ Rẹ̀.

Ó ní láti mú ìránṣẹ́ Rẹ̀, ṣùgbọ́n Ó fi Ohùn Rẹ̀ sílẹ̀, Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ pípé fún Ìyàwó Rẹ̀ Pípé. Nípa gbígbọ́ àti dídúró pẹ̀lú Ohùn Rẹ̀, wọn yóò mọ̀ pé a kò lè tàn wọ́n jẹ.

Ewa gbo o, Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọ́run ṣe gbé Ìjọ Rẹ̀ kalẹ̀, ki gbogbo Ọ̀rọ̀ maa so irú tire! “Ènìyàn kì yóò wà láàyè nípa akara nìkan, bí kò ṣe nípa gbogbo Ọ̀rọ̀ tí ó ń jáde láti ẹnu Ọlọ́run.”

A mọ̀ wipé èyí ni gbígbàgbọ́ nínú gbogbo Ọ̀rọ̀ tí Ẹ̀mí Mímọ́ ń sọ, ṣùgbọ́n nitemi, mo ní ọlá títóbi jùlọ tí a tíì fún ènìyàn rí. Mo lè fi eti mi gbọ́, Ohùn gidi ton sọ gbogbo Ọ̀rọ̀ tí ń jáde láti ẹnu Ọlọ́run.

Kò sí ọ̀nà mìíràn fún mi mo. Ọlọ́run ti pèsè ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà láti gba àwọn ọmọ Rẹ̀ là, ṣùgbọ́n nitemi, Ọlọ́run ti pèsè ọ̀nà pípé láti ṣe ìyàwó rẹ̀ ní pípé.

Lónìí, Sátánì ń ṣi Ìwé Mímọ́ tí a kòsi le fun Iran yi tumo. Yóò jẹ́ kí o mọ̀ pé gbogbo ohun tí Jésù ṣe dára pátápátá. Yóò jẹ́ kí o mọ̀ pé gbogbo ohun tí Arákùnrin Branham ṣe dára pátápátá, òun sì ni wòlíì Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá kan ṣíṣe atunte Ohùn Ọlọ́run tí a ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ nínú ìjọ wọn, wọn yóò sọ pé kii se fun ojo t’ónìí, iṣẹ́ ìránṣẹ́ kan lokan je.

Ohun tí ó ní láti ṣeniyen, eeri? , oun ni láti mu kí àwọn ènìyàn gbaàgbọ́ gegebi woli wa se so, ìyẹn ni—ko jubee lo. Nítorí, “O kò le mú ọ̀rọ̀ kan kúrò nínú rẹ̀, tàbí kí o fi ọ̀rọ̀ kan kún un.” Ṣùgbọ́n ìyẹn ni ohun tí satani ń ṣe.

Kí ni olórí ẹ̀mí rẹ ń gbé lárugẹ nínú ìjọ rẹ? Kí ni Ohùn pàtàkì jùlọ tí Ìyàwó gbọ́dọ̀ gbọ́ lónìí? Olórí kan ṣoṣo ni o lè ní.

A: Ohùn iṣẹ́ ìránṣẹ́?
B: Ohùn Ọlọ́run lórí àwọn fonran?

“Gbogbo irúgbìn gbọ́dọ̀ so irú tirẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọ́run ṣe dá Édẹ́nì Rẹ̀ sílẹ̀.

Èmi kò tako sise iṣẹ́ ìránṣẹ́ gegebi ojise Ólorun. Mo mọ̀, mo sì gbàgbọ́ pé Ọlọ́run ti pè wọ́n. Ṣùgbọ́n nitemi, iṣẹ́ ìránṣẹ́ tòótọ́ yóò sọ fún ìjọ rẹ̀ pé Ohùn lórí àwọn fonran ni Ohùn pàtàkì jùlọ tí wọ́n gbọ́dọ̀ gbọ́, nítorí náà wọ́n gbọ́dọ̀ máa gbo atunte ohun woli nínú ìjọ wọn, nítorí pé ó jẹ́ Ohùn PÀTÀKÌ.

Ní ti èmi àti ilé mi, àti Branham Tabernacle, a ó dúró pẹ̀lú Ọ̀nà Pípé tí Ọlọ́run pèsè. A ó máa tẹe ao si maa gbọ́ Ohùn Ọlọ́run.

Mo fẹ́ kí gbogbo ayé wá dara pọ̀ mọ́ wa láti gbọ́ Ohùn yẹn ní ọjọ́ Àìkú yìí ní agogo méjìlá osan, àkókò Jeffersonville, bí a ṣe tún para pọ̀ yí ọ̀nà tí Ó yàn fún wa lónìí ká.

Arakunrin Joseph Branham

Ìwaasu: Édẹ́nì ti Sátánì 65-0829

Àwọn Ìwé Mímọ́ láti kà kí a tó gbọ́ Ìránṣẹ́ náà:
2 Tímótì 3:1-9
Ìfihàn 3:14
2 Tẹsalóníkà 2:1-4
Isaiah 14:12-14
Matteu 24:24