Eyin Micaiah, owon
Ogun tí o tóbi jùlọ tí a tíì jà ti ṣetán láti bẹ̀rẹ̀ sii farahan bayi. Ọlọ́run ti ń yan àwọn ọmọ ogun rẹ̀ tí ó gbajúmọ̀ fún oti lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́fà ọdún bayi, a sì ti yàn yín láti wà nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun ńlá Rẹ̀.
Ó ti ń wọ yin laṣọ, ó sì ń kọ́ yín logun jija, oju ogun náà sì ti wà níkale, ó ń múra sílẹ̀ láti bẹ̀rẹ̀. Kì í ṣe pé ó ti yàn yín láti wà nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun ńlá Rẹ̀ nìkan ko o, ṣùgbọ́n ó ti yàn yín láti jẹ́ wòlíì Mikaiah nínú ẹgbẹ́ ọmọ ogun Rẹ̀.
Àkókò ti dé, ọjọ́ náà ti dé; ẹ̀yin yóò gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tààràta láti ọ̀dọ̀ ọ̀wọ́n iná fúnrarẹ̀ láti ṣẹ́gun gbogbo ọ̀tá. Ẹ̀yin yóò gba ìtọ́ni pàtàkì, Ọ̀rọ̀ le Ọ̀rọ̀, lórí ohun tí ẹ ó ṣe láti pa gbogbo ẹ̀mí búburú run. Yóò fe gbogbo àìsàn àti gbogbo ise esu tí ó bá wá síwájú yin danu. Kò sí ohun tí ó lè dí yín lọ́wọ́.
Lẹ́yìn ìdánilẹ́kọ̀ọ́ pàtàkì yìí, a óo fi mọro re ro yin lagbára tó bẹ́ẹ̀ tí o e o fi lé gbogbo ibi kúrò. Le èrò ọkàn Buburu jade. Kọ àwọn ìgbàgbọ́ èké sílẹ̀. Kọ àníyàn sílẹ̀. Le àwọn àrùn jade. Kọ ẹ̀ṣẹ̀ sílẹ̀. O óo mọ̀ pé o ti ga juu lo, ati jí o dìde nínú Kristi Jesu, o wà ní ìbi giga ninu awọn ọ̀run, pẹlu gbogbo àwon emi esu lábẹ́ atelẹsẹ̀ rẹ. O óo lóye kíkún o sì gbàgbọ́ pé ìwọ ni Ọ̀rọ̀ náà.
Olorun yióò kọ́ yin ní ohun tí e gbọ́dọ̀ ṣọ́ra fún. Yóò kọ́ yin pé tí ọ̀tá yin bá lè jẹ́ kí e gbàgbọ́ pé Ohun ìjà yin kò lágbára tó, yóò gba ohun ija yin lowo yin.
Ṣùgbọ́n a óo rántí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ wa, gege ọmọ ogun, a óo sì sọ fún satani náà pé: àgbara wa ko, a kò jẹ́ nǹkan kan. Oro Olorun ni Ohun ìjà wa, Yóò sì ṣẹ́gun gbogbo emi Esu, nígbàkúgbà, níbikíbi, nítorí pé Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ ni, Ó sì ti kọ́ wa, Ó sì ti fi hàn wá pé àwa ni Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ tí a sọ di ẹran ara nísinsìnyí. Nítorí náà, esu kò lè ṣẹ́gun wa, àwa ni ẹgbẹ́ ọmọ ogun Ọlọ́run tí a kò lè ṣẹ́gun.
Ọ̀kan lára àwọn ọjọ́ tó ga jùlọ nínú ìtàn ayé ni yóò wáyé ní ọjọ́ ìsinmi yìí. Àwọn Mikaiah rẹ̀ yóò para pọ̀ láti gbogbo àgbáyé lábẹ́ ohùn ọ̀gágun ńlá wọn, níbi tí a ó ti pejopo ní ìṣọ̀kan, láìsí òjìji iyèméjì kankan níbikíbi.
Nígbà náà, tí a bá le gbàgbọ́, tí a sì gbàgbọ́, kò ní sí alailagbára kankan mo ní gbogbo àgbáyé. Tí a bá lè mu ohun gbogbo to, kò ní sí ẹnikẹ́ni tí ó fẹ́ Ẹ̀mí Mímọ́ tí kò ni rigbà, ìwòsàn ọkàn àti ara yóò sì wà loju ese, bí a bá kàn le di ipò wa mú. Àkókò yìí ni. Àwa ni ènìyàn naa. Ẹ̀mí Ọlọ́run ti gbé opagun sókè lòdì sí gbogbo ise esu; àwa jẹ́ Ọ̀kan nínú wọn kò sì sí ohùn tole dawa duro!!
Àwa ti kú sí ìmọ̀lára wa, a ti kú sí ìrònú wa, a ti kú sí gbogbo nǹkan wọ̀nyẹn. Ìgbésí ayé wa farasin a sì sin wá ní Orúkọ Jésù Kristi, a sì jí wa dìde pẹ̀lú Rẹ̀. Àti níbikíbi tí Ó bá wà, a wà níbẹ̀ pẹ̀lú.
Ona abajáde ti la fun wa, satani, n kanra mo yin pelu, “BAYI NI Olúwa wí. BAYI NI OLUWA wí. BAYI NI OLUWA wí.” Asehin wa Asehin bo, a ti ń gbóòórùn afẹ́fẹ́ itura. “BAYI NI OLUWA wí.” Iwo satani, a ti dé, a ti yorí sita. “BAYI NI OLUWA wí, A ti ṣẹ́gun rẹ.”
Kí ni a fi ń ṣẹ́gun Satani?
Ọ̀rọ̀ náà!
Ejẹ́ kí a sọ ọ́; Ọ̀rọ̀! Ọ̀rọ̀! Ọ̀rọ̀!!
Àwọn ìdánilẹ́kọ̀ọ́ itoni míràn
Nígbà tí ọ̀tá bá kọlù e, tí ó sì gbìyànjú láti sọ pé o gbọ́dọ̀ ṣe èyí, o gbọ́dọ̀ ṣe tohun, o kò dára, o kò yẹ, O kò le rí ìwòsàn gbà, o ṣì ní àwọn ìṣòro rẹ kan náà. Kí ni ìwọ yóò ṣe?
Sofun satani wipe “Kúrò lọ́dọ̀ mi.” Ẹ kú o! E fi Ọ̀rọ̀ náà gé e. Yálà ẹ̀mí esu ni, tabi ọ̀tá, ìbáà ṣe àìsàn, ìbáà ṣe àrun, ohunkóhun ti ibaa jẹ́, mú Ọ̀rọ̀ náà kí o sì fi idà fà á. Tí o bá sì lù ú ní ìgbà àkọ́kọ́, tó dà bíi pé kò gbéra, tún lù ú, o lù ú, o sì tún lù ú leekan si.
Ani lati gba Ọ̀rọ̀ náà nítorí pé, “Ọlọ́run sọ bẹ́ẹ̀,” èyí sì ni isan omi láàrín àwa àti Òun. Gbogbo ọ̀nà ti ṣí sílẹ̀ láàrín wa. A ń sọ pé, “Mi ò mọ ìgbà tí màá gbà á, ṣùgbọ́n màá gbà á. Ọlọ́run sọ bẹ́ẹ̀. Gbogbo iyèméjì ti lọ… a tilẹ̀ ń ṣiyèméjì àwọn iyèméjì wa.”
A kọjú ìjà sí esu a sì gba Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Tí mo bá nímọ̀lára tàbí tí mi ò bá nímọ̀lára, ohunkóhun ti ibá ṣẹlẹ̀, Ọlọ́run sọ bẹ́ẹ̀. Oro buse.
Eyin ọmọ ogun, e tele àwon ilana ti doju ami. Emaa tún àwọn Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sọ nígbà tí ọ̀tá bá kọlu yin. Wọn kì í ṣe Ọ̀rọ̀ yin, wọ́n jẹ́ Ọ̀rọ̀ Rẹ̀, Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ kò sì lè kùnà. Ó ti fún wa lágbára láti lo Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ nípa sísọ wá di Ọ̀rọ̀ Rẹ̀. Nígbà tí Sátánì bá kọlu wa, epàṣẹ Oro Olorun fún un.
ÀWỌN ÌTỌ́NI ÀGBÁGBÁ WA
Èyí ni ohun tí mo fẹ́ kí o ṣe gan-an.
Tún majemu yìí wi kí o sì gba gbogbo Ọ̀rọ̀ naa gbọ́ fún ìdande pátápátá.
Sátánì, pada lehin mi! Mo ń jade kuro nibi.
Èmi kò ní dùbúlẹ̀ síbí mọ́. Èmi kò ní joko síbí mọ́. Èmi kò sí ní ilẹ̀ Ogbologbo ti satani mọ́. Mo ń jáde lọ ní òwúrọ̀ yìí.
Idì ni mí.” Àmín! Hallelujah!
Nígbà náà mo fẹ́ kí o ṣe èyí:
Kigbe mo pelu, “BÁYI NI Olúwa wí. BAYI OLUWA WI. BAYI OLUWA WI.”
Ṣí ọkàn rẹ sílẹ̀, sọ pé, “Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ.”
Olúwa, n kò ní fiyèsí bí o ṣe ń semi lára, ohun tí ẹnikẹ́ni nsọ. Mo ń dákẹ́, mo ń fe gbogbo ìrúkèrúdò, àti iyèméjì, àti àìnígbàgbọ́ tí mo ti ní rí kuro lona mi. Gbogbo ìmọ̀lára tí mo ní rí, gbogbo àìsàn tí mo ní rí, gbogbo ohun mìíràn tí mo ní rí, mo ń fe gbogbo wọn danu. Mo ń re gbogbo won koja. Mo ń padà sí ẹ̀mí mi tààrà.
ÌGBÀGBỌ́ rẹ yóò bẹ̀rẹ̀ sí í gòkè sí i. Lẹ́yìn náà, sọ fún un pé, Olúwa, sọ̀kalẹ̀ wá. O sọ pé o ti da mí latí yan ohun ti oba wumi.”
“Ìwọ ni, ọmọ mi.”
Ó dára, mo ṣí ọkàn àti èrò inú mi sílẹ̀.
“Wọlé, Jesu Olúwa ”
Ja Ìgbàgbọ́ gba, idà Ẹ̀mí yẹn, tiise BAYI BI OLUWA WI.
Kígbe, “Hallelujah!” Àmín.
Lẹ́yìn náà, gé gbogbo ọ̀tá tí ó wà níwájú rẹ lulẹ̀. Àmín. Beeni. Gé gbogbo ọ̀tá lule. Tí ó bá jẹ́ pé—ẹ̀mí àtijọ́ tí ó ń mú kí o nímọ̀lára gbogbo nǹkan… Gé nǹkan náà kúrò, pẹ̀lú Ọ̀rọ̀ Olúwa.
ÌTỌ́NI ÌKẸYÌN RẸ̀ Ọ̀MỌ-ogun.
SỌ FÚN Ọ̀TÀ NÁÀ:
Pada lehin mi.” Luu!
Ìwọ fi Ọ̀rọ̀ náà gé e. Yálà ẹ̀mí esu ni, yálà ọ̀tá ni, yálà àìsàn ni, yálà àìlera ni, ohunkóhun tí ibaa jẹ́, mú Ọ̀rọ̀ náà kí o sì fi idà fà á. Tí o bá sì lù ú ní ìgbà àkọ́kọ́, tó dà bíi pé kò gbéra, lù ú lẹ́ẹ̀kan sí i, kí o sì lù ú lẹ́ẹ̀kan sí i, kí o sì lù ú lẹ́ẹ̀kan sí i. Kí o sì lù ú títí tí omaa fi lu ihò kan, bí oromodìyẹ tí ó ń yọ ori rẹ̀ jáde ninu eyin; tàbí idì, ohun ti o ba jẹ́. Yori rẹ sita kuro ninu apo àìsàn àtijọ́ yẹn. Gbé ọ̀nà rẹ jáde, kí o sì wí pé, “Hallelujah!
Eyí tí ó tẹ̀lé da?” Àmín. Ogun niyen. Ọmọ ogun niyen. Ọmọ ogun àgbélébùú ni. Bẹ́ẹ̀ni, sa. Pa gbogbo ọ̀tá run. Kí ló dé? Kí ló dé?
Àwab ni, àwon ọmọ ọba Ábúráhámù tí a ti yàn tẹ́lẹ̀.
Ògo nifun Olorun, gbogbo ọ̀tá ni a ti ṣẹ́gun. Kò sí ohunkóhun tí ó lè dúró níwájú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àwa sì ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Àwa ni Irú Ọmọ Ọba Rẹ̀, gbogbo ìlérí sì jẹ́ TIWA.
Ọjọ́ náà ti dé, Ìyàwó ti gbà gbogbo Ọ̀rọ̀ naa gbọ́, ó sì ń fi sewahu. A ti múra sílẹ̀ nípa gbígbọ́ àti gbígbọ́ Ọ̀rọ̀ Rẹ̀.
Bí ẹ bá nílò ohunkóhun, tí ẹ bá fẹ́ kí a kún yin fún Ẹ̀mí Mímọ́, tí ẹ bá fẹ́ kí a wò yín sàn, tí ẹ bá fẹ́ kí a lé gbogbo emi esu jáde, tí ẹ bá fẹ́ jẹ́ Ìyàwó Kristi, àkókò niyi, gbígbọ́ àti gbígba ohùn Rẹ̀ gbó nibiyi.
Bí ẹ bá fẹ́ nǹkan wọ̀nyí, tí ẹ sì fẹ́ wà níwájú Olúwa, kí ẹsi sún mọ́ Olorun ju bí ti tele lọ, ẹ wá dara pọ̀ mọ́ wa ní ọjọ́ Àìkú ní agogo 12:00 osan, àkókò Jeffersonville, gẹ́gẹ́ bí Ọ̀gágun wa oníràwọ̀ mẹ́rin ṣe ń kọ́ àwọn alágbára Rẹ̀. Iyawo Mikaiah bawo ni a ṣe le ṣẹgun gbogbo eṣu, gbogbo ọta, lati di ominira, ki a si kun fun Ẹmi Mimọ Rẹ̀, ki a si mura silẹ fun Wiwa Rẹ̀ laipẹ.
Àrakunrin Joseph Branham
Iwaasu: Ogun Ti o tobi Julọ Ti A Ti Ja Ri. 62-0311
Awọn Iwe Mimọ:
1 Peteru 5: 8-10
Efesu 6:10-17
Daniẹli 12: 1-7