26-1011 Ìri Ọkùnrin Pípé

Ẹyin aworan okunrin pipe ọ̀wọ́n,

Ẹ̀kọ́ tí a ti ń kọ́. Ohùn Ọlọ́run ti ń sọ̀rọ̀, ó sì ń kọ́ wa, ni Ọ̀rọ̀ le Ọ̀rọ̀, Oro le Ọ̀rọ̀, bí a ṣe lè ṣẹ́gun gbogbo ọ̀tá. Ó ti fi hàn, ó sì ti fi sínú ọkàn wa, ÀWA NI Ọ̀RỌ̀ NÁÀ. Nítorí náà, ota kò lè bori wa.

Nígbà tí ọ̀tá bá ń lépa wa, a kàn ma rora fi oro naá to dabi ado oloro, lama fi Naa, naa, naa, naa daadaa, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí a ti sọ, tí ó ń gbé ninú wa.

Lóòótọ́, a ti te pepe ogun náà kale bayi, ṣùgbọ́n nísinsìnyí kosi ìbẹ̀rù fun wa mọ́; kòsi àníyàn mọ́. A kò gbọ́ ti ẹ̀rí ọkàn wa mo. A kò gbọ́ ti ìrántí wa mo. A kò gbọ́ ti ìfẹ́ okan wa mo. A ti tilekun ọkàn wa mọ́ àwọn nǹkan wọ̀nyí, a sì ti fi Ẹ̀mí Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ sí ọkàn wa àti ookàn aya wa. A ti pa gbogbo nǹkan to lòdì sí Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ run

Gbogbo iyèméjì ti lọ. Gbogbo ìbẹ̀rù ti lọ. Gbogbo ìmọ̀lára iyemeji ti lọ. Gbogbó imolara ti lo. Kò sí ohun tí ó dúró níbẹ̀ bí kò ṣe Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí ń gbé inú wa, Sátánì kò sì le ko èleyi loju

A ń di àgọ́ àyè ti Ọlọ́run alààyè. Ọlọ́run ni ó ń gbé inú wa, ó ń mú kí a dà bí Òun fúnra rẹ̀, ó ń ṣàfihàn ìwà Rẹ̀ nínú wa.

A ń gba ipò Kristi, a ń mu iṣẹ́ ìránṣẹ́ Rẹ̀ tesiwaju. E ń gbé nínu ìrísí ènìyàn bí Ó ti ń ṣàfihàn Ara Rẹ̀ nínú wa. A ní ìjọsìn pípé pẹ̀lú Rẹ̀ nísinsìnyí! Ọlọ́run ni ó ń fi ara Rẹ̀ hàn nínú wa, tí ó jẹ́ àgọ́ Rẹ̀.

Kí ni ìpìlẹ̀ wa tí kò le ye láti gbà àwọn nǹkan wọ̀nyí gbo? ÌGBÀGBỌ́ nio. Ìgbàgbọ́ wa kò sì nílò ohunkóhun; nítorí ìgbàgbọ́ wa gbà Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbọ́. Nítorí ìgbàgbọ́ maa nwá nípa gbígbọ́, àti gbígbọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sì máa nto awon wòlíì nìkan wa, ona kan soso ti a sì lè gbọ́ wòlíì ni nípa títẹ Play… e tee!!

Nípa fífetí sí Ohùn Rẹ̀, a ń fi agbára Rẹ̀ fún wa, a sì ti kú sí ìrònú wa. Ìgbàgbọ́ wa ti di ìgbàgbọ́ ojulowo, a sì ti fi iye Rẹ̀ fún wa. A ti di ẹ̀dá alààyè ti Ọlọ́run, ibùgbé níbi tí Ẹ̀mí Mímọ́ ti lè fi ìbùkún ìmọ́lẹ̀ Rẹ̀ ránṣẹ́ sí wa.

Kí ni Ohùn náà lórí àwọn fonran ń ṣe?

Kristi rán mi láti kọ́ àwọn ènìyàn ni iri Jésù Kristi, kí wọ́n lè jẹ́ ile agbára àti ibùgbé Ẹ̀mí, nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ Rẹ̀. Nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ Rẹ̀, se eri, latí ko enikookan bi ile titi de ipele naa.

Nípa gbígbọ́ Ohùn Rẹ̀, gbígbàgbọ́ àti títẹ̀lé Ọ̀rọ̀ Rẹ̀, ó ti kọ́ wa láti dabi aworan Jésù Kristi; ibùgbé fún Ẹ̀mí Rẹ̀. Àwa jẹ́ ìwà rere aaye, ìmọ̀ aàyè, sùúrù aàyè, ìwà-bí-Ọlọ́run ààyè, Agbára ààyè, tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run alààyè, èyí tí ó sọ wá di ènìyàn alààyè, àwòrán ààyè, bi Ọlọ́run.

Ṣùgbọ́n ara kan ni ìwọ ti pèsè sílẹ̀ fun mi,” Ara tí Ọlọ́run lè gbé inú rẹ̀, ti Ọlọ́run lè rìn nínú rẹ̀, Ọlọ́run lè ríran nínú rẹ̀, Ọlọ́run lè sọ̀rọ̀ nínú rẹ̀, Ọlọ́run lè ṣiṣẹ́ nínú rẹ̀. Àmín! Ohun èlò ààyè ti Ọlọ́run, Ọlọ́run tí ń rìn lórí ẹsẹ̀ méjì, nínú rẹ̀. Ògo nifun Olorun! “Olorun lo nto Ìṣísẹ̀ àwọn olódodo,” Ọlọ́run tí ń rìn nínú yin. “Nítorí ẹ̀yin ni episteli ti a kọ, ti gbogbo ènìyàn n kà á.”

Ògo nifun Olorun…!!! Nítorí náà, a kò bìkítà bóyá a ń gbé nínú àgọ́ tàbí aheré, boya a wa laayè tàbí tabi a kú, tabi ti won sin wa. Èyí nìkan ni ohun tí a nífẹ̀ẹ́ sí, ÌSE IRANSE YÌÍ, Ohùn YÌÍ, tii se Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN. Ìjọba Ọlọ́run ni. Ọ̀nà tí Ọlọ́run pèsè fún wa lónìí ni. Ó ń mo aworan Ọkùnrin Pípé ni, ẹni tí ÀWA JẸ́!

Ẹ jẹ́ kí a pejo papọ̀ kí a sì ṣàyẹ̀wò ìgbésí ayé wa bí a ṣe ń gbọ́ tí Olùkọ́ wa ń kọ́ wa ní ohun tí a gbọ́dọ̀ ṣe, àti bí a ṣe gbọ́dọ̀ gbé ìgbesi ayé PIPE, gege bi awon ọmọkunrin ati omobinrin Ọlọ́run.

A ó ṣèlérí fún Olúwa pé nípa ìrànlọ́wọ́ Rẹ̀ àti nípa oore-ọ̀fẹ́ Rẹ̀, a ó máa gbàdúrà kí a sì máa wá a lójoojúmọ́ láì dáwọ́ dúró, títí a ó fi ní imọ̀lára pé gbogbo ohun tí Ó fẹ́ ń ṣàn nínú ìrísí wa. A ó dúró níbẹ̀ títí a ó fi lè jẹ́ ìfihàn Kristi to mbe lààyè.

Ní ọ̀sẹ̀ kọ̀ọ̀kan, ìdùnnú àti ìrètí ohun tí Olúwa yóò ṣe àti èyí tí yóò fi hàn fún wa kọjá afenusọ. O wumi kí gbogbó agbayé dara pọ̀ mọ́ wa, nítorí pé kò sí ohun tí ó tóbi jù, tàbí tí ó pé ju láti jókòó níwájú Ohùn Ọlọ́run kí o sì di aworan iyawo pípé ti Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ Pípé.

Latí odo Arákùnrin Joseph Branham

Ìwaasu: Ìri Ọkùnrin Pípé 62-1014M

Àkókò: agogo mejila osan. Akoko Jeffersonville, INDIANA.

Awon ese Ìwé Mímọ́:
Matteu 5:48
Luku 6:19
Johanu 1:1 / 3:3 / 3:16 / 5:14 / 14:12
Ìṣe awon Aposteli 2:38 / 7:44–49 / Orí Kẹwàá / 19:11 / 28:19
Efesu 4:11-13
Kolosse Orí Kẹta
Heberu 10:5 / 11:1 / 11:32-40
Jakọbu 5:14
2 Peteru St. 1:1-7
Isaiah 28:19