Ọ̀rọ̀ Ọjọ́ náà
October 15, 2026
Ìgbàgbọ́ ni idaniloju 51-0508
Awon ago ara wa ń kérora, awa sì ní ogún kan. Àwa sì jẹ́ ọmọ nísinsìnyí, àwọn ajogún Ìjọba (kaasa), àwọn ọba àti àlùfáà sí Ọlọ́run tí wọ́n ń rú ẹbọ ẹ̀mí.
Kí ni àlùfáà ń ṣe? O ma n rú ẹbọ ni. Kí ni ẹbọ ẹ̀mí? Ohun tí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin wọ̀nyí ń ṣe nìyẹn, tí wọ́n jẹ́ ọba àti àlùfáà, síbẹ̀ owo wọn kò ti tee ìni won lekunrere, ṣùgbọ́n wọ́n ń rú ẹbọ ẹ̀mí sí Ọlọ́run: èso ètè wa tí ń yìn ín (Àmín.), èso ètè wa.
Ẹ le so wipé, “Arákùnrin Branham, kò wu mi láti yìn ín.” Àkókò náà niyi láti rú ẹbọ náà. Ẹ yìn ín labe isakoso boti wù kio rí. Àwọn ọba àti àlùfáà, àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin tí ń rú ẹbọ ẹ̀mí, àwọn èso ètè wa, to n fi iyin fun Orúkọ Rẹ̀.
Oúnjẹ Ojoojúmọ́
Ẹ yin Olúwa, gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdè: ẹ yìn ín, gbogbo ènìyàn.
Orin Dafidi 117:1