Ọ̀rọ̀ Ọjọ́ náà
October 16, 2026
Ipeni lejo 63-0707M
Báwo ni wọ́n ṣe fi ẹ̀sùn kàn án? Nítorí pé esìn won kò gbà á, ati wipe oto ni biwon se moo nínu ọkàn wọn. Ṣébi Nikodemu ninu iwe Johanu Mímọ́ ori keta, o fi èleyí han dáadáa? “ O ni, Rábì, àwa, Farisí,” àwa oníwàásù, àwa olùkọ́ni, “awa mọ̀ pé olùkọ́ni ni ọ́ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wa ni iwo ise, nítorí pé kò sí ẹni tí ó lè ṣe àwọn kàn tí ìwọ ń ṣe wonyi bikosepe Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀.” Ẹ sa wo o? Wọ́n jẹ́rìí si ní gbangba nípasẹ̀ ọ̀kan lára àwọn ènìyàn olókìkí wọn, wọ́n sì ń sè é…nítorí eko adabowo wọn, wọ́n kan Kristi mọ́ àgbélébùú.
Lónìí kò sí ẹni tí ó lè ka ìwé Ìṣe awon Aposteli 2:38 gẹ́gẹ́ bí mo ṣe maa kà á, àti awon ese iwe mimo miran, gẹ́gẹ́ bí mo ṣe maa kà á. Ṣùgbọ́n nítorí esìn adabowo wọn, àti nítorí àwọn ìwé ẹ̀rí wọn tí wọ́n fi njeun ti wọn, ndi kakiri lai mo wipàmì ẹranko buburu naa ni; wọ́n sì fi àwọn nǹkan wọ̀nyẹn kni, wọ́n nfi owọn ara won kàn Jesu Kristi mọ́ àgbélébùú lẹ́ẹ̀kan sí i, wọ́n sì n kàn án mọ́ àgbélébùú níwájú gbogbo ènìyàn, wọ́n sì n sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run kan náà tí ó ṣèlérí láti ṣe èyí, won wa n mú ebi wá sórí ìran náà.
Oúnjẹ Ojoojúmọ́
Ó to awon tirẹ̀ wa, àwọn tirẹ̀ kò sì gbà á.
Johannu 1:11