Ọ̀rọ̀ Ọjọ́ náà

Ọ̀rọ̀ Ọjọ́ náà
October 17, 2026

Iwe Hébérù Orí Kejì #2 57-0825E

Wòlíì àgbà náà ti ko gba gbere, wo ojú obìnrin náà. Ó ní, “Kokọ lo, se àkàrà fún mi na” Esaa wo iru aṣẹ bee, ki ọkùnrin kan dede sọ fún obìnrin opó kan tó ń kú lọ, tí ebi ń pa, pé kí ó kọ́kọ́ bọ́ oun. Kí ló wi? “Nítorí pé BAYI NI OLUWA WI, koko iyefun re kò ní ṣófo, bẹ́ẹ̀ ni kolobo oróró re kò ní gbẹ, títí Ọlọ́run yóò fi rọ òjò sórí ilẹ̀ aye.”

O kọ́kọ́ se ti Olorun, Ó wọlé, ó sì se àkàrà kékeré naa, ó sì wá fún wòlíì. Ó padà sẹ́yìn, ó sì se òmíràn, òmíràn, òmíràn, àti òmíràn. Ikoko iyefun náà kò sì ṣófo, kolobo oróró ko gbẹ, títí Ọlọ́run fi rọjò sórí ilẹ̀ ayé. Ó fi Ọlọ́run ṣáájú àwọn ọmọ rẹ̀. Ó fi Ọlọ́run ṣáájú ohunkóhun mìíràn. Ó koko gba Ìjọba Ọlọ́run ní àkoko.

Ọlọ́run gbọ́dọ̀ ní ipò àkọ́kọ́ nínú ọkàn rẹ, ipò àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé rẹ, ipò àkọ́kọ́ nínú gbogbo ohun tí o bá ṣe tàbí ohun tí o jẹ́. Ọlọ́run gbọ́dọ̀ jẹ́ àkọ́kọ́. Kò fẹ́ ipò kejì. ipò kejì. Eyí tó dára jùlọ lo tosi Olorun, àti gbogbo ohun tí a ní. Ó yẹ fún un. Ìbùkún ni fún Orúkọ Mímọ́ re Rẹ̀!

Oúnjẹ Ojoojúmọ́
… Ki iwọ ki o fi gbogbo àiya rẹ, ati gbogbo ọkàn rẹ, ati gbogbo agbara rẹ, ati gbogbo inu rẹ fẹ Oluwa Ọlọrun rẹ; ati ẹnikeji rẹ bi ara rẹ.
…
Lúùkù 10:27

An Independent Church of the WORD,