Ọ̀rọ̀ Ọjọ́ náà
October 18, 2026
Jíjí Jésù loju orun 63-0117
Nísinsìnyí, Olorun wa ninu Jesu, Olorun wa ninu
Kristi, ó ń bá ayé laja sodo ara rẹ̀.” Àwọn ènìyàn wọ̀nyí sì gba ẹ̀rí Rẹ̀ gbọ́. Àwọn tí wọ́n sì gbà á gbọ́ ní tòótọ́ lè ri ibukun gba lowo Ọlọ́run. Nígbà tí wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀, Ó sọ pé, “ase jade lara oun” Ase je “agbára.” Ó…Ní ede mìíràn, tí a bá lè sọ ọ́ lónìí: Ó di aare mu nígbà tí àwọn ènìyàn bá fà ase iwòsàn jade lara re. Ó dára, tí ó bá ṣiṣẹ́ bẹ́ẹ̀ nínú ara ènìyàn yẹn, yóò ṣiṣẹ́ nínú ara ènìyàn mìíràn.
A sì ń dá àgbegbe yi arawa ká, olúkúlùkù wa. Boya o ti wà pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí wọ́n jẹ́ ènìyàn rere, ṣùgbọ́n ágbára kaka ni o fi le duro nitosi wọn. Bakana náà ni o ti wà pẹ̀lú àwọn ènìyàn mìíràn tí o kàn fẹ́ láti wà ní àyíká wọn. Iwo lomaa dá àgbegbe yẹn sílẹ̀. Àti, wipe, ṣé kò ní wu o láti wà ní àyíká Jésù fúngbà díẹ̀ bi? Iyanu leyi je!! Wo bí àgbegbe tí Jesu dá yẹn ìbá ti jẹ́, mo rò pé ó jẹ́ ebun ìfẹ́ nla, owo àti ìbẹ̀rù iwa bi Ọlọ́run
Oúnjẹ Ojoojúmọ́
Ọ̀nà Olúwa jẹ́ agbára fún àwọn olódodo:
Òwe 10:29