Ọ̀rọ̀ Ọjọ́ náà
October 14, 2026
Àwọn Kanga tí ó ti Fọ́ 65-0123
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dàbí ẹ̀wọ̀n kan; o fi n kọjá lori ọ̀run-àpáàdì. Ibi tí ewon naa ti ṣe aláìlera jùlọ ni agbara rẹ̀ wa, Ọlọ́run sì fẹ́ kí a pa gbogbo Ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́. Ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ Bíbélì nìyẹn; jijà ti won ja ọ̀rọ̀ kan ṣoṣo lo ko iran eniyan sínú òkùnkùn ikú.
Jésù wá ní àárín Bíbélì, Ó sì sọ pé, “Ènìyàn kì yóò wà láàyè nípa akara nìkan, bí kò ṣe nípa gbogbo Ọ̀rọ̀.” Kì í ṣe apá kan nínú àwọn ọ̀rọ̀ náà, tàbí mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún; ṣùgbọ́n gbogbo ọ̀rọ̀ ni, gẹ́gẹ́ bí Éfà àti Ádámù se wa.
Ní ìparí Bíbélì pẹ̀lú, nínú ìwé Ìfihan 22:18, Ó wi pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá yo ọ̀rọ̀ kan kúrò nínú èyí, tàbí tí ó fi ọ̀rọ̀ kan kún un!”
Nítorí náà, kí ló dé tí a fi nílò láti fi èrò ènìyàn kún èyí, nígbà tí èyí jẹ́ èrò Ọlọ́run fúnra Rẹ̀ nípa rẹ̀?
Oúnjẹ Ojoojúmọ́
Nítorí pé ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè, ó sì lágbára, ó sì mú ju idà olójú méjì lọ…
Hébérù 4:12