Ọ̀rọ̀ Ọjọ́ náà
August 2, 2026
Iṣẹ́ iyanu Kejì 51-0729E
Kò jale lati fọwọ́ sí ohunkóhun tí Satani ba gbe wá fun o. Ó gbọ́dọ̀ gbà nkan e padà. Sọfun wipé, “Mo kọ̀ láti gbà á. Mi ò ní gbà á rárá, rárá se.” Ó gbọ́dọ̀ dà á padà ní Orúkọ Olúwa. Tí o bá gbà á gbọ́, tí o sì jẹ́wọ́ rẹ̀, tí o sì sọ pé, “Mo ti gba Jésù Kristi gẹ́gẹ́ bí Olùwòsàn mi,” kò sí iponju tàbí àrùn tó lè dúró lara rẹ. Duro ti oro eri re.
Ṣùgbọ́n nígbà àkọ́kọ́ tí o bá rẹ̀wẹ̀sì tí o sì wipé, “enn Bẹ́ẹ̀ ni, mo ṣì ní aisan yen” Loju ese lo maa subu pada sí ibi tí o wà tele. O ti fọwọ́ sí i, o si tun gbà á padà. O sọpé, “Bẹ́ẹ̀ ni, Ọ̀gbẹ́ni satani èmi—yióo gbà á padà.” Ah, arákùnrin.
Iwo dúró síbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí—níwọ̀n ìgbà tí èémí bá si wà nínú rẹ, sọ pé, “Mo kọ̀ láti gbà á. Mo kọ̀ láti gbà á.” Ti won ba bie lere wipe báwo ni ìmọ̀lára rẹ ṣe rí? Dahun wipe “Ó dára, hallelujah.” Bo seri niyen. Bẹ́ẹ̀ ni. Fi iru eda tí Olorun dá ọ hàn satani; Ẹ̀mí Ọlọ́run ti tún o bí, o kò sì ní láti forí balẹ̀ fún àwọn ère Satani. Dúró níbẹ̀, sọ pé, “Mi ò fẹ́ nǹkan rẹ.”
Ti satani ba bio leere wipe “Kí ló dé, orúkọ rẹ nìyí lara rẹ̀, dókítà sọ wipe…”
Iwo na dáa lohun wipe “Emi kò bìkítà fún ohun tí dokita sọ. Mo mọ ohun tí Ọlọ́run sọ. Maa gberue lo Iwo esu”
Bẹ́ẹ̀ ni o, ọ̀wo ti a ni láti fi mu esu nìyẹn; ẹ dá a padà fun. Òun ni ẹni tí ó fún yín, òun naa ni yóò gbà nkan e padà.
Oúnjẹ Ojoojúmọ́
Nitorina ẹ tẹriba fun Ọlọrun. Ẹ kọ oju ija si Èṣu, on ó si sá kuro lọdọ nyin.
Jákọ́bù 4:7