Ọ̀rọ̀ Ọjọ́ náà
October 21, 2026
Ẹ lọ wi fún àwọn ọmọ-ẹ̀hìn mi 53-0405S
Nígbà tí wòlíì yìí wọnú ẹ̀mí lo, Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí í fi ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ hàn án; wipé ẹnìkan yóò wà tí yóò ko ẹ̀ṣẹ̀ arayé lo, tí yiò sì tún jíǹde kuro ninu oku. Ó rí àjíǹde Olúwa wa. Mo feran èyí, nígbà tí mo bá rònu. Ó dìde. Ó gboran nu.
Ó ńjoko lori aatan eérú . Kaasa! Lode oni, amaa dasa pe ori burúkú ti wo ilé rẹ̀ ni. Gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ ti kú tan. Gbogbó orọ̀ rẹ̀ ti lọ. Koni alafia ara mo. Ó joko síbẹ̀, Kristiani si ni o, tàbí onígbàgbọ́, ó joko síbẹ̀, awon eniyan ti keyin si. Awon eeyan, àní ìjọ rẹ̀ pàápàá, ti keyin sí. Ó joko síbẹ̀, ó ń họ́ oju egbò rẹ̀.
Nígbà tí Ẹ̀mí Olúwa si bále, tí ó sì rí owuro ojo àjíǹde naa, ẹe gbo, ó dìde dúró, ó sì wí pé, “Emi mọ̀ pé Olùdànde mi mbe láàyè, àti ní ọjọ́ ìkẹyìn, yiò dúró lórí ilẹ̀ ayé. Bí ìdin tile je eran ara yìí, síbẹ̀ nínú ara mi ni èmi yiò rí Ọlọ́run; Ẹni tí èmi yóò rí fún ara mi-…” Ó mọ̀ pé òun yiò rí I ní ọjọ́ ìkẹyìn, nítorí pé àjíǹde yóò wàye, àjíǹde gbogbogbòò.
Oúnjẹ Ojoojúmo
Nitori emi mọ̀ pe Oludande mi mbẹ laãyè, ati pe ni Ojo ikẹhin, yio dide lori ilẹ.
26 Ati lẹhin igba ti idin eran ara mi ba je eran ara yi run, síbe, ninu eran ara mi li emi yiò ri Olorun.
Jobu 19:25-26