Ọ̀rọ̀ Ọjọ́ náà
October 12, 2026
Èlíjàh, kilo gbo? 59-0412E
Ariwo koni afi n mo àwọn ohun nla ńlá. Kii se awon nkàn alariwo. Ale gbe kẹ̀kẹ́ akeru kan lọ sí oko; nígbà tí a bá ti ja eru re sílẹ̀, yóò máa se gbagara gbugburu ni, yóò sì máa pariwo púpọ̀. Sugbon nígbati ó ba n padà to ona to ti baje yen pelu eru ire oko nínu re, kò tìle ní dún rárá. Kí ló dé? Óti rẹrù ni. Ohun tí ìjọ nílò ní alẹ́ yìí ni láti kún fún ẹrù, kí a ru eru tokun fun ìfẹ́ Ọlọ́run.
Oòrùn lè fa galoonu omi oke aimoye lai pariwo pupo, to ariwo ìgbati a ba fe pon omi ero ife kan soso jáde. Bẹ́ẹ̀ ni. Àwọn—àwọn ọ̀run lè ro ìrì kárí gbogbó agbayé to je wipe ariwo re ko tile ni to ariwo ti omi ti efi nwon koriko ayika ile npa lo. Dájúdájú. Ǹjẹ́ e ti fi eti yin gbọ́ bí àwọn aye miran se ma ń yí padà rí? Àwọn ohun ńlá ma nlo jẹ́jẹ́ ni.
Ẹ kiyesi Ẹ̀mí Mímọ́ nígbà tí Ó bá wọlé ní asalẹ́ yìí, bí Ó ṣe ń se ohun gbogbo ni idákẹ́ jẹ́ẹ́ tó. Ṣùgbọ́n awa ń lépa àwọn ìjo fofo ára, a ń sáré lé àwọn nǹkan kéékèèké, a sì ń kùnà láti gbọ́ ohùn naa.
Oúnjẹ Ojoojúmọ́
Ṣugbọn Oluwa mbẹ ninu tempili rẹ̀ mimọ́; jẹ ki gbogbo aiye pa rọ́rọ niwaju rẹ̀.
Habakuku 2:20