Ọ̀rọ̀ Ọjọ́ náà
October 9, 2026
Ìbẹ̀rẹ̀ àti Ìparí Ìran Àwọn Kèfèrí 55-0109E
Dáníẹ́lì ti jó gbogbo àwọn afárá lẹ́yìn rẹ̀. Kò pete pèrò láti padà sẹ́yìn mọ́. Kò boju wẹ̀hìn mo. Ó ń wò waju, ó ti ko àwọn ohun atijo sílẹ̀. Ó n tẹ̀síwájú sí àmì ìpè gíga. Ìyẹn ni ohun tí a gbọ́dọ̀ máa ṣe. Ohun toye ki Ìjọ máa ṣe nìyẹn.
Bí mo ṣe kíyè sí i, nígbà náà, Ọlọ́run gbà kí Sátánì dán an wò. Wọ́n sì dán wọn wò, pẹ̀lú iná. Wọ́n dán wọn wò, pẹ̀lú, nípa ihò kìnnìún. Ní gbogbo ìṣẹ́jú, Ọlọ́run ko wọn yo, won ju aṣẹ́gun lọ.
“Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ìdánwò àwọn olódodo, ṣùgbọ́n Ọlọ́run gbà á lọ́wọ́ gbogbo wọn.” Ẹ wo bí èyí ti jẹ́ ìyanu tó! a mọrírì èyí gaan ni. Àwọn ámiwò, ìpọ́njú, ìdánwò, gbogbo wọn ń ṣiṣẹ́ po fún rere! Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, Ọlọ́run a wa rí i wipé Óun lè gbẹ́kẹ̀lé ọ, lẹ́yìn náà Ó máa ṣe àwọn ohun ribiribi fún ọ.
Oúnjẹ Ojoojúmọ́
Ṣugbọn nigbati a ba ndá wa lẹjọ, lati ọwọ́ Oluwa li a ti nnà wa, ki a má bã dá wa lẹbi pẹlu aiye.
1 Kọ́ríńtì 11:32