Ọ̀rọ̀ Ọjọ́ náà
July 10, 2026
Eese ti iwo fi nkepe mi? Sọ̀rọ̀!
63-0714M
Ayé wà ní ipò ti o wa lowolowo yi. Orílẹ̀-èdè náà wà ní ipò tirẹ̀ lowolowo yi. Àwọn obìnrin náà wà ní ipò tiwon wa lowolowo bayi. Àwọn ọkùnrin náà wà ní ipò tiwon wa náà bayi. Ìjọ náà wà ní ipò tiwon wa bayi. Ohun gbogbo wà níbẹ̀. À nri awọn apeere, àwọn àmì, àwọn eda abami ton farahan ton poora loju orun, àti onirunru awon nkan kayeefi, àti riru omi òkun, iji tonja lori okun, ijaya ati iberu l’ọkàn awon ènìyàn, awon ìdààmú àkókò yi, wàhálà láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, ìjọ npada seyin kuro nínu igbagbo.
Àti ọkùnrin ẹ̀ṣẹ̀ ni tí dìde, tí ó gbé ara rẹ̀ ga ju gbogbo ènìyàn lọ; tabi awon tí a ń pè ní Ọlọ́run, ẹni tí ó jókòó ní tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run, tí ó ń fi ara rẹ̀ hàn, kaasa! , ó sì ti dé s’orílẹ̀-èdè yìí. Ìjọ náà sì ti di eleto meto, gbogbo wọn sì npéjọpọ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn pansaga kekeeke se je si iya awon agbere nla ni, ohun gbogbo ti di oro agbere ti emi gaan ni.
Kínni ise agbere? Sísọ fún àwọn obìnrin pé wọ́n lè gé irun wọn, sísọ fún àwọn obìnrin pé wọ́n lè wọ ṣókoto penpe, sisọ fún àwọn ọkùnrin pé wọ́n lè ṣe èyí àti pé wọ́n le ṣe tohun; ati awọn oniwaasu, wọn nṣe eyi, ati ihinrere igbalode ati awọn nkan bee. Ṣe eko rii pe o jẹ sise panṣaga pẹlu Ọrọ otitọ Ọlọrun bi?
Ọlọrun si ti fi Ọrọ otitọ Rẹ ranṣẹ si wa, laini eko adamo, ko fipa muni, o si fun wa ni Ọwọn Ina, Ẹmi Mimọ ti o ti wa pẹlu wa fun ọgbọn ọdun bayi. Ati ohun gbogbo ti O ti sọ tẹlẹ ati ti O si ti nsọ, won nwa si imuṣẹ gẹgẹ bi Olorun ti wi.
Ounjẹ Ojoojumọ
Ṣugbọn opin ohun gbogbo kusi dede: nitorina ẹ maa wa ni airekoja, ki ẹ si maa ṣọna pelu adura.
1 Peteru 4:7