Ọ̀rọ̀ Ọjọ́ náà
July 14, 2026
Mo woye wipé Woolii ni iwọ ise 53-0614E
Oju ntimi bi mose maa nwo aṣọ àwoleke ti o ti gbo bi akisa yẹn. Nígbà tí mo bá lọ si ibi ipàdé àwọn oníwàásù, mo máa ń gbé apá ọ̀tún mi sórí aṣọ yìí báyìí, mo sì máa ń na ọwọ́ òsì mi siwon lati bowon lowọ́. Mo máa ń sọ pé, “Ẹma binu fun ọwọ́ òsì mi; ó sún mọ́ ọkàn mi.” Èmi asi máa bowon lowo. Ohun tó wà níbẹ̀ ni pé, mi ò fẹ́ kí wọ́n rí aṣọ awoleke mi ti oti dabi akisa.
Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn Arkansas, tí wọ́n dúró níbẹ̀ tí wọ́n sì rí bi Angẹli Ọlọ́run tí ń rìn láàárín àwọn ènìyàn náà, wọ́n ń gbìyànjú láti fọwọ́ kan aṣọ àwoleke mi ti o ti gbo ni. Bí ọ̀pọ̀ ènìyàn sì ti ń fọwọ́ kan aso naa, wọ́n ń rí ìwòsàn. kì í ṣe nítorí aṣọ àwoleke to ti gbo yen ko o, nítorí wọ́n gbàgbọ́ pé Ọlọ́run wà láàárín wọn ni.
Jẹ́ kí n sọ èyí ní asalẹ́ yìí: Ó ṣeé ṣe kí n má wọ aṣọ àwoleke ti oti ya náà, ṣùgbọ́n Ọlọ́run kan náà tó wà níbẹ̀ ní alẹ́ ojo yẹn wà níbí ní alẹ́ yìí láti ṣe ohun kan náà. Ó jẹ́ okan náà lánàá, lónìí àti títí láé. Ọ̀nà kan ṣoṣo tí ẹ ó fi lè rí èrè gbà láti inú ohunkóhun tí o je ti Ọlọ́run, eni lati ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀, kí ẹ sún mọ́ ọn pelu okan otito, ki esì gbaàgbọ́. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ń rí ìwòsàn gbà, nítorí wọ́n ń wá pelu èrò ọkàn tó tọ́, wọ́n si gbàgbọ́ pé òtítọ́ wà níbẹ̀, atí wipe tiwọ́n bá sì lè sún mọ́ ọn, wọn yóò rí ìwòsàn gbà. Ọlọ́run sì ń fi idi Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ mule.
Oúnjẹ Ojoojúmọ́
Ó sì wí fún un pé, Dìde, máa lọ: ìgbàgbọ́ rẹ ti mú ọ láradá.
Lúùkù 17:19