Ọ̀rọ̀ Ọjọ́ náà
July 11, 2026
Irúgbìn irukerudo 65-0118
Judas kàn fi ijo ṣeré lásán ni. Kò jẹ́ olóòótọ́ gidi. Kò ní ìgbàgbọ́ ní tòótọ́; ki bá tí da Jésù. Ṣùgbọ́n, wò ó, ó gbin irúgbìn rukerudo yẹn. Ó rò pé òun lè bá ayé ṣọ̀rẹ́, iyen mammoni,
kí òun sì tún ní ìbádọ́rẹ̀ẹ́ pẹ̀lú Jésù, ṣùgbọ́n ó ti pẹ́ jù fún un láti wa nkan se si oro naá. Nígbà tí àkókò ikú dé, nígbà tí ó ṣe ohun búburú yìí, ó kọjá aala láàárín lílọ síwájú àti pípadà sehin. Ó ní láti máa bá ọ̀nà tí ó ntọ̀ lọ, gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́tàn. Ó gbin irúgbìn rukerudo, ó gbìyànjú láti rí ojúrere lọ́dọ̀ àwọn ijọ ńlá nla ìgbà náà,iyen pẹ̀lú àwọn Farisi àti Sadusi. Ó sì rò pé òun yóò ṣare pa owo die sapo ara rẹ̀, kò sì di olókìkí láàrín àwọn ènìyàn. Irú èyí lon fa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn láti da rukerudo sile loni, tí wọ́n ń gbìyànjú láti rí ojúrere lọ́dọ̀ ènìyàn! Awa ni tiwa o, ejẹ́ kí a wa ojúrere lọ́dọ̀ Ọlọ́run, kì í ṣe lọ́dọ̀ ènìyàn. Ṣùgbọ́n ohun tí Júdásì ṣe niyen nígbà tí o jere fifurugbin rukerudo.
Oúnjẹ Ojoojúmọ́
Ẹ̀yin ará Gálátíà alainironu, ta ló tàn yín jẹ, kí ẹ má baà gbọ́ òtítọ́…
Gálátíà 3:1