Ọ̀rọ̀ Ọjọ́ náà
July 8, 2026
Ibẹ̀rẹ̀ àti iparí iran awọn Kèfèrí 55-0109E
Dáníẹ́lì ti jó gbogbo àwọn afárá tí ó wà lẹ́yìn rẹ̀. Kò gbèrò láti padà sẹ́yìn mọ́. Kò boju wẹ̀yìn wo mo. Ó ń wò iwaju, ó ko àwọn nǹkan atijo sílẹ̀. Ó tẹ̀síwájú sí àmì ìpè gíga. Ìyẹn ni ohun tí a gbọ́dọ̀ máa ṣe. Ohun tí Ìjọ yẹ kí ó máa ṣe nìyẹn.
Bí mo ṣe kíyè sí i, nígbà náà, Ọlọ́run gbà kí Sátánì dán an wò. Wọ́n sì dán wọn won wò, pẹ̀lú iná. Wọ́n dán wọn wò, pẹ̀lú, nípa ihò kìnnìún. Ní gbogbo re, Ọlọ́run mú wọn jáde, awa ju aṣẹ́gun lọ.
“Ọ̀pọ̀ ni ìdánwò àwọn olódodo, ṣùgbọ́n Ọlọ́run gbà á lọ́wọ́ gbogbo wọn.” Ẹ wo bí èyí ti jẹ́ ìyanu tó! Ẹ wo bí a ṣe mọrírì èyí tó. Àwọn ìdánwò, ìpọ́njú, ìdánwò, gbogbo wọn ń ṣiṣẹ́ po fún rere ni! Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, Ọlọ́run lè rí i nígbà náà pé Ó lè gbẹ́kẹ̀lé ọ, lẹ́yìn náà Ó máa wa ṣe àwọn ohun ńlá fún ọ.
Oúnjẹ Ojoojúmọ́
Ṣùgbọ́n nígbà tí a bá dá wa lẹ́jọ́, Olúwa ń nà wá, kí a má baà dá wa lẹ́bi pẹ̀lú ayé.
1 Kọ́ríńtì 11:32