Ọ̀rọ̀ Ọjọ́ náà
July 7, 2026
Ọ̀nà tí Ọlọ́run ti la sile
53-0613
Ọlọ́run fi wá wé àgùntàn. Mo ń woye wipe kini ìdí rẹ̀. Nje enikẹ́ni níbí tí sin àgùntàn rí? Ó dáa, se e mọ̀ pé àgùntàn ni eran osin tikole ran ara re lọ́wọ́ jùlọ layé yi, nígbà tí ó bá sọnù. Kò lè mọ̀ bi yio se pada delé rárá. Ṣé bẹ́ẹ̀ lori o eyin olùtọ́jú àgùntàn? Emi gaan ti bawọ́n tọ́jú awon aguntan ri ní pápá ìwọ̀ oòrùn, mo sì ti kó opo awọn agunte lọ jeun.
Ṣùgbọ́n kíyèsí, nígbà tí aguntan bá sọnù… nígbà tí ó bá sọnù, yóò dúró yí ó sì maa ké loju kan ni. Gbogbo ǹkan to lese niyẹ̀n. Àwọn ìkookò yóò si paa je.(Oti tan nìyẹn.), ‘àfi ti olùṣọ́ àgùntàn bá wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ náà ni ó rí fún wa, nígbà tí a bá sọnù, a kò ní ìrètí rárá àyàfi tí Olùṣọ́ Àgùntàn bá dé tí ó sì gbà wá.
Nítorí náà, inú mi dùn ní asalẹ́ yìí pé Ọlọ́run ti fi Olùṣọ́ sori agbo agùntàn rẹ̀, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́ ni? Wipé nígbà tí a bá kepèe, Ó máa ń gbọ́ nígbà gbogbo…
Oúnjẹ Ojoojúmọ́
Ó máa Máa bọ́ agbo ẹran rẹ̀ bí olùṣọ́-àgùntàn: yóò kó àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn jọ pẹ̀lú apá rẹ̀, yóò sì gbé wọn sí àyà rẹ̀.
Aísáyà 40:11