Ọ̀rọ̀ Ọjọ́ náà
July 6, 2026
Àwọn Àsehinwa ati asehinbo Ìpinnu 55-1008
Ó wí pé, “Ṣùgbọ́n eṣẹ gbọ́dọ̀ wà lori eṣẹ, ìlà lórí ìlà. die níhìn-ín díẹ̀, lohun, kí o sì di èyí tí ó dára mú ṣinṣin. Nítorí pẹ̀lú ètè akololo àti ahọ́n mìíràn ni èmi yóò fi bá àwọn ènìyàn yìí sọ̀rọ̀, èyí sì ni ìsinmi naa.” Àmín.
Hébérù 4 sọ pé, “Ìsinmi kan ṣì ku fún àwọn ènìyàn Ọlọ́run, nítorí àwa tí a ti wọ inú ìsinmi Rẹ̀ ti sinmi kúrò nínú iṣẹ́ wa gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti ṣe kúrò nínú ise tirẹ̀.”
Ọlọ́run ṣiṣẹ́ fún ọjọ́ mẹ́fà, ní ọjọ́ keje, ó sinmi, kò sì padà wá mọ́. Ènìyàn lè ṣiṣẹ́ ní ayé yìí títí ó fi di ọmọ ogún ọdún, ọgbọ̀n ọdún, ogójì ọdún, àti àádọ́rin ọdún, ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá dáwọ́ iṣẹ́ ayé rẹ̀ dúró, ó nlọ sí ìsinmi ayérayé pẹ̀lú Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti ṣe ní ìbẹ̀rẹ̀.
Ah, arákùnrin, tí o bá ń gbé ní eti ààlà ní alẹ́ yìí, wá rekọjá. Rekọjá Jordani. Ó jẹ́ ohun ìyanu. Àwọn èso àjàrà ńláńlá wà níbí. A rí ẹ̀rí àkọ́kọ́, a rí…Hallelujah. A ní àwọn Joshua àti Kalebu tí wọ́n ti kọjá ààlà náà tí wọ́n sì mú ẹ̀rí padà wá pé Ilẹ̀ rere ni. Gbogbo ìlérí tí Ọlọ́run ṣe wà níbí yi. Ìhìnrere kíkún, Bíbélì kíkún, ìwòsàn àtọ̀runwá, ayọ̀, idunnu, àlàáfíà, gbogbo ohun tí Bíbélì ṣèlérí, gbogbo èso lowa ní ilẹ̀ yìí. Àmín.
Oúnjẹ Ojoojúmọ́
Nítorí eṣẹ gbọ́dọ̀ wà lórí eṣẹ, ìlànà lórí eṣẹ; ìlà lórí ìlà, ìlà lórí ìlà; díẹ̀ nihín, díẹ̀ lohun: Nítorí pẹ̀lú ètè àti ahọ́n mìíràn ni yóò fi bá àwọn ènìyàn yìí sọ̀rọ̀.
Isaiah 28:10-11