Ọ̀rọ̀ Ọjọ́ náà

Ọ̀rọ̀ Ọjọ́ náà
July 5, 2026

Ìpìlẹ̀ Ìdapo pelu Olorun 61-0214

Ṣùgbọ́n nísinsìnyí, a rí i pé ohun tí ó mú kí ènìyàn fẹ́ láti ni idapo ni wipé ó ti ní ìbáṣepọ̀ tẹ́lẹ̀ ri. Àti ìbáṣepọ̀ rẹ̀ wà pẹ̀lú Ọlọ́run. Awọn eniyankan ń gbìyànjú pelu gbogbo agbára won, láìni ikasi ohun tí wón jẹ́. Bí ó bá jẹ́ ará Íńdíà; nígbà tí a dé síbíyi, a rí ará Íńdíà kan tí ó ń foribale fun oòrùn, tí ó ń jọ́sìn fun igi orisa idile kan. A lọ sí Áfíríkà a bawọn lábẹ́ àwọn òrìṣà kéékèèké àti àwọn ǹkan miran. Ibì kan wà tí ó ń gbìyànjú láti wá ọ̀nà rẹ̀ padà, nítorí pé ìpilẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ni láti bá Ọlọ́run ni idapọ̀. Ibẹ̀ ni ó ti wá. Ó mọ̀ pé óun ti wá láti ibì kan lẹ́yìn aṣọ ìkélé, ó sì ń gbìyànjú láti wo ẹ̀yìn níbẹ̀ láti wo ibi tí ó ti wá àti ibi tí ó n padà si. Ìdí nìyẹn tí agbára àtọ̀runwá fi nfa àkiyèsí àwọn ènìyàn gidigidi nítorí pé àwọn ènìyàn ń wo ibi tí wọ́n ti wá àti ọ̀nà tí wọ́n nto lọ.

Ìwé kan ṣoṣo ló wà ní ayé tí ó lè sọo fún ọ, ìyẹn ni Bíbélì: ẹni tí ìwọ jẹ́, ibi tí o ti wá, àti ibi tí o ń lọ. Bẹ́ẹ̀ gan-an ni; Ó nsọ ibi tí o ń lọ fún ọ níbí nínú Bíbélì, àti ibi tí o ti wá àti ẹni tí o jẹ́.

Oúnjẹ Ojoojúmọ́
Nítorí mo dá a fún ògo mi, mo ti dá a; bẹ́ẹ̀ ni, mo ti ṣe é.
Isaiah 43:7

An Independent Church of the WORD,