Ọ̀rọ̀ Ọjọ́ náà
July 4, 2026
Ọ̀nà ti Ọlọ́run la sile fún wa
52-0900
Gbogbo ohun tí Ólorun ní nínú Ìjọba rẹ̀ tiwa ni. Ó kan mú gbogbo ìwé ńlá tí ó kún fún ìwé ṣowe dowo, ó sì ti buwolu ni ìsàlẹ̀, ó wí pé, “woo, ọmọ mi. Ohunkóhun tí o bá nílò, lọ gbà á.” Àmín.
Má bẹ̀rù láti ko iye ti o fe sori sowedowo naa. Ko iye ti o fe sori re ki o sì fi lé e lọ́wọ́, wí pé, “O ṣeun, Olúwa.” Hallelujah! Beeni yio ri.
“Ohunkóhun tí o bá fẹ́,” Máàkù 11:24, “nígbà tí o bá ngbàdúrà, gbàgbọ́ wipé o óò ri gbà á, ìwọ yóò si rí i gbà.”
Buwo lu ṣowe dowo náà, ki o si so wípé, “Olúwa, mo nílò ìwòsàn.” fa awe sowedowo na ya, ki o si wípé, “Wò ó, Olúwa, mo béèrè fun iwosan ní orúkọ Jésù.” So wípé “Ẹ ṣeun, Olúwa,” kí o sì máa ba tire lọ, ẹ gbà Olorun gbo fún ìwòsàn yin. Esì adura yin yio si padà wá lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Gégé bi àwọn ẹyẹ iwo tí ń gbe oúnjẹ wa fun Èlíjàh. Bi oti ri gaan niyen.
Oúnjẹ Ojoojúmọ́
Ohun gbogbo ni ṣiṣe fun Olorun.
Mátíù 19:26