Ọ̀rọ̀ Ọjọ́ náà
July 3, 2026
Ẹlẹ́ṣẹ̀ tó burú jùlọ ní ìlú 56-0218E
Ṣùgbọ́n díẹ̀ lára àwọn tó ń sọ pé Kristẹni ni wọ́n lónìí ní ilẹ̀ wa ló kan mo die nípa Ọlọ́run. Ah! Wọ́n mọ gbogbo ẹ̀sìn wọn, sugbon won ko mọ Ọlọ́run.
Ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, ìyẹn ló sì mú kí Ó jẹ́ ẹni ńlá loju mi. Ohun tó mú kí Ó jẹ́ ẹni gidi fún mi ni láti rò pé Ó fẹ́ wá sí aye kíi se se lati jẹ́ ẹni ńlá, tabi lati je olorúkọ ńlá, tàbí irú nǹkan bẹ́ẹ̀. Ó sọ ara rẹ̀ di onírẹ̀lẹ̀, ó sì di ìránṣẹ́ fún gbogbo wọn. Jésù Olúwa mi ni. Ẹni tí mo fẹ́ràn nìyí; òun niyen, mo fẹ́ fi gbogbo ayé mi fún un láti sìn ín, àti láti ṣiṣẹ́ fún un, kí n sì ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe láti jẹ́ kí àwọn ènìyàn maa wò ó, kí wọ́n gbà á gbọ́, kí wọ́n sì fẹ́ràn rẹ̀. Ó dára. Iyebíye ni Jesu je simi.
Nígbà tí ó di ẹni tí ń fọ ẹsẹ̀, ó mú aṣọ ìnura, ó roo mọ́ra, ó sì fọ ẹsẹ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn re, ó wípe, “E je ki enití ó tóbi láàárín yín jẹ́ ìránṣẹ́ fun gbogbo eniyan.” Àpẹẹrẹ ti Jesu fi lele nìyẹn.
Oúnjẹ Ojoojúmọ́
Ẹ fi ìrẹ̀lẹ̀ wọ̀ ara yín: nítorí Ọlọ́run kọjú ìjà sí àwọn agbéraga, ó sì fi oore-ọ̀fẹ́ fún àwọn onírẹ̀lẹ̀.
1 Pétérù 5:5