Ọ̀rọ̀ Ọjọ́ náà

Ọ̀rọ̀ Ọjọ́ náà
July 2, 2026

Nkan adiitu (Paradox) 62-0128A

Jesu, nígbà tí ó wà l’ayé, ó rìn lórí omi. Fi imo ijinle sayenyi sàlàyé èleyí fún mi. Sọ fún mi bí ènìyàn ṣe lè rìn lórí omi: àdiitu nio. Ní ọjọ́ kan, ó mú akara márùn-ún àti ẹja méjì ó sì fi bọ́ awon eniyan ẹgbẹ̀rún márùn-ún . Irú iwukara wo ni Jesu lo? Esi wa wo o, eja naa ti ku. Nígbà tí ó bù akara náà, ó bù ú kúrò lara akara kan ni…Nígbà tí ó fi le awon omo ehin re lowo, ki Jesu to da ọwọ́ rẹ̀ padà, akara mìíràn ti pada si ibi ti o ti bu t’akoko. E ranti wipe won ti kore àlìkámà na kuro nínú oko, won ti sèe tẹ́lẹ̀, òróro ti wa lara re. (Ẹe ri?) Gbo eelo ounje tiwa lara akara na. Jesu mu eja kan, Ó bù ú kúrò lara re, ẹja mìíràn tí a ti sè si pada si oju ibi ti Jesu ti buu. Àmín. Hallelujah.

Olorun ti fún wa ní oro ase naa, o dara lati dúró nínú Ọ̀rọ̀ náà. Ẹ dúró níbẹ̀. Mo gbàgbọ́ pé a wà nítosi imuse ileri na, yi o sele nisoju wa laipe. Ẹ je olòotọ́ sí Ọ̀rọ̀ náà.

Ounje Ojoojúmọ́
Ṣùgbọ́n gbogbo àwọn tí ó gbà á, ó fún wọn ní agbára láti di ọmọ ti Ọlọrun, ani si awọn ti o gbagbọ ninu orukọ rẹ̀:
Johannu 1:12

An Independent Church of the WORD,