Ọ̀rọ̀ Ọjọ́ náà

Ọ̀rọ̀ Ọjọ́ náà
July 1, 2026

Jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ yín tàn kedere níwájú àwọn ènìyàn 61-0903

Ọ̀nà kan ṣoṣo tí a lè gbà rí Kristi ni nígbà tí ó bá ń ṣe àfihàn ara re nínu iwo ati emi. Mo rí Kristi nínú rẹ. O rí I nínú mi. Bẹ́ẹ̀ ni a ṣe ń wo Kristi. Bi mo ba wá sí ìpàdé ti mo bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù. Mo ma ń wo àwọn ènìyàn. O lè rí bóyá wọ́n ní ìfẹ́ sí i tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, laarin iṣẹ́jú díẹ̀. O ń wo oju àwọn olùgbọ́ rẹ. O lè mọ̀ bóyá o ń dawon lagara tàbí bee ko. O rí i? Ohun àkọ́kọ́ tí o mọ̀ ni pé, o rí wọn tí wọ́n joko sibẹ̀, tí wọ́n ń rọ̀ mọ́ gbogbo oro ti mon nso, pelu ìfojúsùn ti o lagbara. O rí i? Mo ń rí Kristi tí ó ń farahan nínú ẹni yẹn, nítorí pé ebi ń pa á, òùngbẹ sì ń gbẹ ẹ́ fún Ọlọ́run.

Lẹ́yìn náà, olugbo mi, nri ifarahan kristi tí mo ń wàásù ìhìnrere re nínu mi. Emi naa si nrí Kristi nínú rẹ̀. Èyí túmọ̀ sí wípé Kristi wà láàrín wa nígbà náà. Àmín. “Ẹ̀bi ń pa á, òùngbẹ sì ń gbẹ ẹ́.” Mo maa ń wo àwọn olùgbọ́ mi, bí wọ́n ṣe ngbà oro naá. Bi mo ba so nǹkan mìíràn, ewo ipa ti yoo ko lara wọn. Emaa ri wipe imole ń tàn loju won, tí ó kún fún ayọ̀. Wọ́n ti múra tán nígbà náà láti ri esi gba lodo Olorun. Kristi niyen. Mo rí wipe Kristi ń fara han nínú ẹni náà, nítorí pé Ìhìnrere, ani Ìhìnrere Kristi tí ó rọrùn, ti ribi gbe nínu ọkàn yẹn, nítorí pé ebi ń pa wọ́n, òùngbẹ sì ń gbẹ wọ́n fun oro Olorun.

Oúnjẹ Ojoojúmọ́

Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ Kristi máa gbé inú yín lọ́pọ̀lọpọ̀ …
Kolosse 3:16

An Independent Church of the WORD,