Ọ̀rọ̀ Ọjọ́ náà

Ọ̀rọ̀ Ọjọ́ náà
June 30, 2026

Ọlọ́run Iran Buburú Yìí 65-0801M

Ṣùgbọ́n, nínu ìgbọràn, Obìnrin kékeré yìí, tí ó ń gbé nípa ìgbàgbọ́, iyen iyàwó Kristi; ẹni tí ó wà níbí, níbẹ̀; níbí, ní ibòmíràn, ìjọ mìíràn, ijo eleko adamo mìíràn, ohunkóhun tí ibaa jẹ́, nínú àwọn kan kò… Ó gbà Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbo, ó gbọ́ràn, ó ń dúró nínú ìfẹ́, fún ifidimúlẹ̀ ileri ti Olorun se fun Iran yi. Ó ń foju sona fun. ara Ọ̀rọ̀ náà loje, ó sì ńlepa ki ìgbésí ayé Rẹ̀ le fi Ọ̀rọ̀ náà hàn.

Ẹ̀yin ará, nje oro mi yee yin? Mo nírètí pé ìyẹn kò fo yín ru.

Ara ń dúró fún (èyí tí í ṣe ti Ọ̀rọ̀ náà), ó ń dúró de Ìyè (èyí tí í ṣe Ẹ̀mí naa) láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ tàbí láti sọ ọ́ di ààyè. Ohun tí iyawo Kristi ndúró dè nìyẹn. Kò sí ona iye miran tí yóò ṣiṣẹ́ nínú rẹ̀. Kò lè wá laayè nípase ọ̀nà mìíràn. Síbẹ̀, Ó nímọ̀lára rẹ̀ níbẹ̀, Ó sì mọ̀ pé yóò ṣẹlẹ̀; Osi ṣẹlẹ̀ looto. Lẹ́hìn náà ni iyawo kristi jí. Ọlọ́run wí pé, “Jẹ́ kí ó wà,” Ó sì jáde wá bí Eefa àkọ́kọ́ tí jáde wá.

Oúnjẹ Ojoojúmọ́
Ẹ jẹ́ kí a yọ̀, kí a sì yọ̀, kí a sì fi ọlá fún un: nítorí ìgbéyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn ti dé, aya rẹ̀ sì ti múra sílẹ̀.
Ìfihàn 19:7

An Independent Church of the WORD,