Ọ̀rọ̀ Ọjọ́ náà

Ọ̀rọ̀ Ọjọ́ náà
June 29, 2026

Ọlọ́run Tí Ó fi ara rẹ̀ pamọ́ ninu irele
63-0412E

Ọlọ́run kii mú kí àwọn nǹkan díjú, awon nkan bi adura gbigba ni ilana ijo Aguda, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ bi, pe ka dara pọ̀ mọ́ ijo yí tabi ijo miran, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀kọ́, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀kọ́ ìle eko Bibeli. Sise eyi n’ mu wa jìnnà sí Ọlọ́run nigbogbo ìgbà ni.

Lónìí, a jẹ́ onímọ̀ sáyẹ́ǹsì debi wipe a fi lèe sọ iye àwọn etu ibon tí a le fi ṣe ado oloro, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ; a sì le salaye bi a se po won papo ti wonfi di ado oloro ton bu gbamu! Sùgbọ́n a nte ewe koríko tutu mole a kòsi lè ṣàlàyé bi ose nhu to ndagba.

Ọlọ́run, nínu iwa irele. Ọlọ́run fi ara rẹ̀ hàn nínu ìrele. Ó sọ ara rẹ̀ di enyan yepere. Ó se eleyi kí àwọn ọlọ́gbọ́n má lè lóye. Jésù wí pé, “Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, Baba, ìwọ ti fi èyí pamọ́ kúrò loju àwọn ọlọ́gbọ́n àti amoye, ìwọ sì nfi í hàn fún àwọn ọmọdé tí o fe kẹ́kọ̀ọ́.”

Má ṣe gbìyànjú rara láti mo Ọlọ́run nipa eko eniyan. Tí o bá ṣe bẹ́ẹ̀, eko naa yio muo jina s’ọ́dọ̀ Ọlọ́run. Ṣé o rí i? A kii mọ Ọlọ́run nípa ẹ̀kọ́. Ọlọ́run, nípa ìgbàgbọ́ ni afi n moo. Àti ìkọlù àkọ́kọ́ tí satani ṣe lórí ètò ẹ̀kọ́ ni, ènìyàn sì pàdánù ìbáṣepọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run. Bẹ́ẹ̀ gan-an ni. Ó gbọ́dọ̀ mọ Ọlọ́run nípa ìgbàgbọ́, kì í ṣe ohun tí ó lè ṣàlàyé; nípa ohun tí ó gbàgbọ́, sugbon tí o kò lè ṣàlàyé re ni.

Oúnjẹ Ojoojúmọ́
Kí ìgbàgbọ́ rẹ má ṣe dúró nínú ọgbọ́n ènìyàn, bí kò ṣe nínú agbára Ọlọ́run.
1 Kọ́ríńtì 2:5

An Independent Church of the WORD,