Ọ̀rọ̀ Ọjọ́ náà

Ọ̀rọ̀ Ọjọ́ náà
June 28, 2026

Emi ni, má bẹ̀rù 60-0329

Ọkọ̀ ojú omi kékeré náà bí ó ti ń sáré kọjá lo lori omi. Ó nilati jẹ́ wipe àkókò yẹn ni Sátánì gbera dìde, t’ósì wí pé, “Ah! owo mi ti te wọn, awon nìkan ni kosi Jesu nibe. Àkókò mi nìyí láti gbesan lara wọn, nítorí wọ́n ti ń lé àwọn ẹ̀mí èṣù mi jáde àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Nítorí náà, èmi yóò gbesan lara won” Ìgbà náà ni Sátánì yóò lè gbesan laraa re. Nígbà tí ó bá rí i pé o ti lọ láìsí Jésù.

Ìgbà náà i Sátánì yóò ri ìjọ mu. Nígbà tí o bá ní ìfẹ́ sí nǹkan mìíràn yàtọ̀ sí ìpàdé àdúrà, nígbà tí o bá ní ìfẹ́ sí i débi pé— ìdàgbàsókè ti eran ara ka e lara ju ìdàgbàsókè t’ẹ̀mí lo. Rántí pé Sátánì mbowà pade rẹ̀. Ó ti ri e mu láìsí Jesu nibẹ̀.

Ọlọ́run o, àdúrà mi ni wipe ki o so ìjọ ji padà sí ìgbà àtijọ́, ìpàdé àdúrà ní gbogbo òru. Jí àwọn ènìyàn re dìde sí—ayíká ẹ̀mí. Ó gba èyí láti mú àwọn ọmọdé wá sínú Ìjọba náà. Ó gba ayíká emi.

Oúnjẹ Ojoojúmọ́
…nítorí láìsí mi ẹ kò le ṣe ohunkóhun.
Jòhánù 15:5

An Independent Church of the WORD,