Ọ̀rọ̀ Ọjọ́ náà

Ọ̀rọ̀ Ọjọ́ náà
June 27, 2026

Ọ̀nà tí Ọlọ́run ti pèsè
53-0613

Kì í ṣe bẹ́ẹ̀—kò pọndandan kí ẹnikẹ́ni lọ sí ọ̀run àpáàdì. Ọlọ́run kii rán ẹnikẹ́ni lọ sí ọ̀run àpáàdì. Iwo lo maa rán ara rẹ lọ sí ọ̀run àpáàdì. Ọlọ́run ti ṣe gbogbo ohun tí ó lè ṣe ní ayé láti dè o lonà ati lọ sí ọ̀run àpáàdì. Síbẹ̀síbẹ̀, o pinnu láti lọ sí ọ̀run àpáàdì. O fo gbogbo idena tí Ọlọ́run gbé kalẹ̀ sí ọ̀nà rẹ koja; osa n ranri mo
“Èmi kò gbà èleyí gbo, Èmi kò sì gbà tohun gbo, Èmi kò sì gbà èyí. gbo” Osa n ranri moo

Nísinsìnyí, iná pupa kan wà ní ìlú yi. Ó sì ntan pupa àti alawo ewéko. Èyí ló máa n sọ ìgbà tí o lè dúró tabi ki o tesiwaju. Tí o bá rufin, má ṣe dá ìjoba lẹ́bi. Wọ́n ri iná náà síbẹ̀ fún ààbò rẹ ni. Ṣùgbọ́n tí o bá sáré kọjá nibẹ̀, Ebi re ni. Ìwọ lo da ara re lebi.

Oúnjẹ Ojoojúmọ́
Yóò fi òdodo ṣe ìdájọ́ ayé, àti àwọn ènìyàn pẹ̀lú òtítọ́ rẹ̀.
Sáàmù 96:13

An Independent Church of the WORD,