Ọ̀rọ̀ Ọjọ́ náà
August 20, 2026
61-0216 Àmì Ẹranko naa àti Èdìdì Ọlọ́run Apa kini
Awọn ero ti Kainì nro lokan ni wipe “Èmi yóò fi àwọn nǹkan wọ̀nyí rúbọ.” Ṣùgbọ́n loju temi, ẹbọ Abeli kò fi bee dára. Ó ṣeé ṣe kí won ma ni okun toyi kankan ní ọjọ́ náà, nítorí náà ó gbọ́dọ̀ jẹ́ pé Abeli so okun igi àjàrà kan mo orun ọ̀dọ́ àgùntàn kékeré naa, ó nfà á lọ síbẹ̀, ó sì tee sorí okuta. Kò ní abẹ tàbí ọ̀bẹ mínú nígbà náà, nítorí náà óni lati je wipe o mú—òkúta kan, ó fa orí re kékeré sẹ́yìn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í re ọrùn kékeré rẹ̀. Bí odo aguntan na sì ti bẹ̀rẹ̀ sí í ké ton tapa, ti ẹ̀jẹ̀ sì ń sàn lórí rẹ̀, ẹ̀jẹ̀ ń ṣun jade lara re, on kigbe, oń kú lórí àpáta …
Apere kini í ni eyi je? Ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ọdún lẹ́yìn náà, a pa Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run lórí àpáta ayérayé, eje re nsan, ó ń kigbe, ó ń fi èdè miran soro bí ó ti ń kú lo lórí igi Kalfari. “Ah, Iwo Ọ̀dọ́ Àgùntàn tí ń kú, Ẹ̀jẹ̀ re iyebíye kì yóò so agbára rẹ̀ nu títí a of fi ra gbogbo ìjọ Ọlọ́run padà ti won koni dẹ́ṣẹ̀ mọ́.” Àwọn ètò ẹ̀kọ́ wa, àwọn ètò ìjo eleyameya kolee ribe. [Arákùnrin Branham tá ìka ọwọ́ rẹ̀—]; yóò gba Ẹ̀jẹ̀ Jésù Kristi nikan, kosi ohunkóhun mìíràn tole ṣe é. Bẹ́ẹ̀ni.
Oúnjẹ Ojoojúmọ́
Wọ́n sì ṣẹ́gun rẹ̀ nípa ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Àgùntàn naa àti nípa ọ̀rọ̀ ẹ̀rí wọn; wọn kò sì fẹ́ràn ẹ̀mí wọn títí doju ikú.
Ìfihàn 12:11