Ọ̀rọ̀ Ọjọ́ náà

Ọ̀rọ̀ Ọjọ́ náà
August 19, 2026

Heberu Orí Kẹta 57-0901M

Nípa ẹ̀sìn àti ìgbàlà kan ṣoṣo tí a ní, àti ìfẹ́, owà láàrín àwọn ènìyàn oniwa bi Olorun tòótọ́. Ẹ mọ̀, Bíbélì sọ pé èyí yóò ṣẹlẹ̀. [Ìjọ sọ pé, “Àmín.”] Enhen. Ẹ̀yin olùka Bíbélì, mo gbọ́ tí ẹ ń sé “Àmín,” to rinle ,àti ẹ̀yin oniwàásù towa lehin lohun. Bẹ́ẹ̀ ni, o dara bee. Ìfẹ́ otito yió jìnnà rere, ní igba ìkẹyìn; ìfẹ́ kan ṣoṣo tí yóò kù, yóò wà láàrín àwọn Àyànfẹ́ nínú àwọn ènìyàn Ọlọ́run. “Baba yóò kehin sí ìyá, àti ìyá yóò lòdì sí baba, àti àwọn ọmọ yóò kehin sí àwọn òbí, àti àwọn onirunrú eniyan yio kehin sí ara wọn.” Ìfẹ́ kan ṣoṣo tí yóò kù ni, yóò wa laarin awon ayànfẹ́ naa, àwọn Àyànfẹ́ nìkan. Ọ̀rọ̀ náà ti a pe ni “Àyànfẹ́” wá láti inú ọ̀rọ̀ ná ti a pe ni “Àwon ti ati yànfẹ́,” àwọn ènìyàn tí Ọlọ́run yàn.

Oúnjẹ Ojoojúmọ́
Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yóò di pupọ̀, ìfẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ yóò tútù.
Mátíù 24:12

An Independent Church of the WORD,