Ọ̀rọ̀ Ọjọ́ náà
August 18, 2026
Ọkùnrin Inúu ni 53-1212
Gbo, arákùnrin, ẹ jẹ́ kí a padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run, s’odo Ọlọ́run alààyè, Ẹni tí o jínde, ife ní oruko re, Ẹni tí kò bọ̀wọ̀ fún àwọn ijo eleyameya kankan, tí ó sì bọ̀wọ̀ fún gbogbo wọn ní ọ̀nà mìíràn, Ẹni tí ó feran gbogbo ẹ̀dá owo rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, tí ó sì fẹ́ sọ̀kalẹ̀ wá. Ó ti ṣe gbogbo ohun tí ó lè ṣe láti le sọ̀kalẹ̀ sínú ọkàn àwọn ènìyàn.
Ó ti pèsè ọ̀nà kan bí ejò idẹ. Ó ti pèsè Jésù láti ba gbogbo aini wa pade nínú ìrìn àjò wa láàrín ọ̀run àti ayé. Ìyẹn ni… Ó pèsè Jésù Kristi oun si ni ebọ arufin ati aruda ti Ọlọ́run. Ohun Gbogbo tí o nílò ní alẹ́ yìí kò sí nínú ìjọ rẹ; ó wà nínú Kristi. Níbẹ̀ lowa. Kò sí nínú ẹ̀kọ́ rẹ; kò sí nínú ẹ̀kọ́ ti o ko nile eko bibeli, tabi eko adabowo re, ohun tí ìwọ…Ó wà nínú Jésù Kristi.
Wo Jesu pẹ̀lú ìgbàgbọ́, ìfẹ́ pelu írẹ̀lẹ̀, kí o sì wí pé, “Ọlọ́run, wẹ̀ mí mọ́ kuro ninú gbogbo ìmotara eni nikan mi, kí o sì mú gbogbo ẹ̀gbin kúrò lara mi, kí n sì jẹ́ tìrẹ pátápátá láti òní lọ.” Ki o ma wo ohun tí Ọlọ́run yóò ṣe fún ọ.
Oúnjẹ ojoojúmọ́
Nítorí ojú Olúwa wà lara àwọn olódodo, etí rẹ̀ sì ṣí sí àdúrà wọn.
1 Pétérù 3:12