Ọ̀rọ̀ Ọjọ́ náà

Ọ̀rọ̀ Ọjọ́ náà
August 17, 2026

Ija laarin Ọgbọ́n ati Ìgbàgbọ́ 62-0401

“Ní àtètèkọ́ṣe ni Ọ̀rọ̀ wà, Ọ̀rọ̀ sì wà pẹ̀lú Ọlọ́run, Olorun si ni Ọ̀rọ̀ náà. Ọ̀rọ̀ náà sì di ara.” Erò Ọlọ́run si farahan nínú ago ara ènìyàn, “Ó di ara, ó sì ń bawa gbé.” Se oye yin?

Nísinsìnyí, tí o bá ní Ìyè Àìnípẹ̀kun lónìí, o wà nínú Ọlọ́run. Nípa wíwà Ọlọ́run ninú re, ìwọ ni èrò Ọlọ́run tí a sọ jáde. Kaasa! Nígbà náà, má ṣe fetí sí eyikeyi èrò ogbon eniyan, kí a má baà gba adé rẹ, fi fún ẹlòmíràn. Má ṣe gba èyíkéyìí ero eniyan rárá. Kàn gbà ohun tí Ọlọ́run sọ gbọ́ wipe otítọ́ ni, kí o sì dúró pẹ̀lú rẹ̀.

Àwọn èrò, nípasẹ̀ ọgbọ́n eniyan, a maa gbìyànjú láti jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ náà sọ ohun tí kò sọ ni.

Oúnjẹ Ojoojúmọ́
…nitoriti awa tikarawa ti gbọ́ ọ̀rọ rẹ̀, awa si mọ̀ pe, nitõtọ eyi ni Kristi na, Olugbala araiye.

An Independent Church of the WORD,