Ọ̀rọ̀ Ọjọ́ náà

Ọ̀rọ̀ Ọjọ́ náà
August 16, 2026

Àwọn Ìdókòowò 63-1116B

Nínú Ìwe ifihàn ori keta, a kà nipa Ìjọ Laodekia, eyi je afihan ọ̀kan lára ​​àwọn ifihan tí ó bani nínú jẹ́ jùlọ nínú gbogbo Bíbélì, iwe Ìfihàn ori keta, ní Ìjọ Laodekia. Gbogbo àwọn ìjọ yòókù, nínu igba ijo Luther, àti Àkókò Ìjọ Méje, olúkúlùkù, kò sọ nípa bi Jesu sewà ní ita, “Ẹni tí ó wà nínú ìjọ ni.” Ṣùgbọ́n ní igba ijo Laodekia, Ó wà ní ita, ó ń kanlẹ̀kùn, ó ń gbìyànjú láti padà wọlé. Ohun ti o seni laanu julo gbáà ni láti ronú, pé, “Ọmọ Ọlọ́run, ó ń kanlẹ̀kùn ijo tire, ó ń gbìyànjú láti padà wọlé.”

Ṣùgbọ́n ọrọ̀ ayé yìí ti fọ́wọn loju. Kì í ṣe oro owó nìkan, ṣùgbọ́n ọ́rọ̀ ní gbajúmọ̀ sise, ọ́rọ̀ ní àwọn nǹkan ayé, àníyàn ìle ayé, eti fi ara nu ara yin debi wipe, àwọn ọlọ́gbọ́n ti wọlé tí wọ́n sì ti gba ọkà náà moyin lowo, ìyẹn—Perli iyebíye náà. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti yan àwọn ènìyàn kan tẹ́lẹ̀ láti wà níbẹ̀; ẹnìkan yóò wà níbẹ̀. Ṣùgbọ́n wọ́n kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Kìí ṣe gbogbo wọn ni yóò koo sile; àwọn kan nínú wọn yóò gbà á.

Oúnjẹ Ojoojúmọ́
Àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé Olúwa yóò dàbí òkè Síónì, tí a kò le ṣí nidi, ṣùgbọ́n tí ó wa títí láé.
Orin Dafidi 125:1

An Independent Church of the WORD,