Ọ̀rọ̀ Ọjọ́ náà
August 15, 2026
Rironu lai ni idaniloju pe bee loro ri
62-0117
Ẹnìkan sọ pé, “Jẹ́ kí ọkàn rẹ ṣófo nísinsìnyí. Wo ojú ọ̀run tààrà. Jẹ́ kí ọkàn rẹ ṣófo. O máa ní ìrírí kan.” Mase siyèméjì si ohun tí o nṣe. Ótitọ́ ni. Ṣùgbọ́n, o fe ní ìrírí kan ni, ṣùgbọ́n iru ìrírí wo ni? Oo rí i? nígbà tí o bá ṣe èyí, o kàn ṣí ọkàn rẹ sílẹ̀ fún Sátánì ni. Yóò fún ọ ní nǹkan kan miran. Òótọ́ ni.
Ṣùgbọ́n, mo rò pé, ẹni tí ó ba ń bọ̀ wá s’ọ̀dọ̀ Kristi yẹ kí ó wá pẹ̀lú gbogbo ọgbọ́n tí ó ní, àti sise asaro nínú ọkàn rẹ̀, nígbà tí wọ́n bá nbo lọ̀dọ̀ Olorun, gbogbo ìlérí nínú Ìwé Mímọ́. Jeki ọkàn rẹ waní igbaradi nigbàti o ba nbo lọ̀dọ̀ Kristi. Má ṣe jẹ́ kí ó ṣófo. Esu yóò mú ọ ṣe ohunkóhun. Oo ri? Wọn yóò fún ọ ní ìmọ̀lára kan. Satani lè ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú. Ṣùgbọ́n ìwo fẹ́ ni ìrírí kan, iriri ohun tí Bíbélì fi kọ́ni, ohun kan tí ó jẹ́ arigbamu.
Oúnjẹ Ojoojúmọ́
… nitori emi mọ̀ ẹniti emi gbagbọ́, o si da mi loju pe, on le pa ohun ti mo fi le e lọwọ mọ́ titi di ọjọ nì.
2 Tímótì 1:12