Ọ̀rọ̀ Ọjọ́ náà

Ọ̀rọ̀ Ọjọ́ náà
August 14, 2026

Ibi Ìjọsìn Tí Ọlọ́run Yàn 65-0220
Kíyèsí, ìbi kansoso ti Oluwa yan ni ààbò wà, nínú ọ̀dọ́ àgùntàn Rẹ̀, àti ní orúkọ ọ̀dọ́ àgùntàn náà.

Kíyèsí, ó jẹ́ “ako” ọ̀dọ́ àgùntàn, ako sini, kì í ṣe abo odo aguntan. Kì í ṣe ìjọ, to je obinrin; ṣùgbọ́n Orúkọ okunrin ni, kì í ṣe orúkọ obinrin. Ibi tí Ó ti fe lọ pàdé àwọn ènìyàn re ki se ní orúkọ abo odoaguntan, ṣùgbọ́n ní Orúkọ ako odoaguntan naa!

Wàyí a le sọ pé, “Ìjọ́ naa, ìjọ ńlá, alágbára, ó ṣe èyí ó sì ṣe tohun. Ó ti la akoko ìjì lile koja. A ti ni omo ijọ to po. A ti pọ̀ ní iye. Ìjọ ńlá ni wá. Ó jẹ́ ohun ńlá.”

Ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò sọ ohunkóhun nípa ijo tii se obìnrin, Ó sọ pé, “Òun, iyen okinrin.” “Òun,” ni ibi ìpàdé naa, Ọ̀dọ́ Àgùntàn naa, kì í ṣe ìjọ náà. Kì í ṣe orúkọ obinrin, ṣùgbọ́n Orúkọ okunrin. Kò fi orúkọ Rẹ̀ sinú obinrin kankan. Ó fi Orúkọ Rẹ̀ sínu “re, okunrin naa”!

Ìdí nìyí tí ó fi sọ pé, “Gbogbo ohun tí a ba nse, l’ọ̀rọ̀ tàbí ni ìṣe, a gbọ́dọ̀ ṣe ohun gbogbo ní Orúkọ Jésù Kristi.” Tí a bá ngbàdúrà, a gbọ́dọ̀ gbàdúrà ní Orúkọ Jésù. Tí a bá nbẹ̀bẹ̀, a gbọ́dọ̀ bebe ní Orúkọ Jésù. Tí a bá nrìn, ki a máa rìn ní Orúkọ Jésù. Tí a bá nsọ̀rọ̀, ki a máa sọ̀rọ̀ ní Orúkọ Jésù. Tí a bá ń ṣe ìrìbọmi, a gbọ́dọ̀ ṣe ìrìbọmi ní Orúkọ Jésù Kristi. Nítorí, “Ohun gbogbo tí a bá nse ní ọ̀rọ̀ tàbí ní ìṣe, emaa ṣe é ní Orúkọ Jésù Kristi.”

Oúnjẹ Ojoojúmọ́
Ohunkóhun tí ẹyin bá si nṣe ní ọ̀rọ̀ tàbí ní ìṣe, ẹ maa se ohun gbogboní orúkọ Jesu Kristi Oluwa, kí ẹ si máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run àti Baba nípasẹ̀ rẹ̀.
Kolosse 3:17

An Independent Church of the WORD,