Ọ̀rọ̀ Ọjọ́ náà
August 21, 2026
Kristi ti ako se l’alejo” 55-0911
Nísinsìnyí, báwo ló ṣe ṣẹlẹ̀? Báwo ló ṣe lè rí bẹ́ẹ̀? Báwo ni eni to nfo ese awon alejo yẹn ṣe jẹ́ kí Jésù kọjá? Jesu wani ikale, ó jókòó níbi oúnjẹ alẹ́, níbi oúnjẹ alẹ́, pẹ̀lú ẹsẹ̀ to doti. Ó jókòó nibikan ni igun ilé. Ah iba se wipe emi ni eniti nfo ese awon alejo yen ni. Iba wumi kí n ti gba ipò rẹ̀. Jésù nìyí, lọ́nà kan…
Dajudaju o ti fo ẹsẹ̀ omowe Jones. Ó ti fo ese gbogbo àwọn iyòókù. Ó ti fo ese won, ó sì ti fi òróró kùn wọ́n. Símónì fẹnu kòo, oti ki kaabo. Wọ́n wa níbẹ̀, wọ́n tì sewon lalejo gidigidi. “Óò, Omowe Jones, nje o mo nkankan? Ní ijosi, ní Ile Farisí lágbájá…Ṣé o rántí farisí Lágbájá? Ṣé o rántí?” Ó, won so opọ̀ oro nípa katakara títí tí wọ́n fi kùnà [Arákùnrin Branham kan orí àga ìjókòó nígbà mẹ́rin—] láti rí asiko ti Jésù wọlé.
Mo sì ń woye lónìí, nje bóyá a jẹ́ omo ijo Mẹ́tọ́díìsì, tàbí omo ijọ Onítẹ̀bọmi, omo ijọ awon agba koti fo wa loju, ti a kò rí bi Jésù tí nwọlé. Ọlọ́run, ṣàánú!
Oúnjẹ Ojoojúmọ́
Wọ́n npe arawon ni ọlọ́gbọ́n, sugbon wọ́n di asiwere
Róòmù 1:22