Ọ̀rọ̀ Ọjọ́ náà

Ọ̀rọ̀ Ọjọ́ náà
July 31, 2026

Heberu Orí Karùn-ún àti kẹ́fà Apa kini
57-0908M

Baba ọ̀run, awon eeyan yi ń bọ̀ nípa ìgbàgbọ́, nípasẹ̀ oore-ọ̀fẹ́. Nǹkan bí ọwọ́ méjìlá ló wa lókè. Àwọn èso ìse iwaasu yi ni. Wọ́n ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ. Wọ́n gbàgbọ́. Mo ni igbàgbọ́ nínú wọn pẹ̀lú, Olúwa. Mo gbàgbọ́ pé, ní tòótọ́, Ẹ̀mí Mímọ́ lo bá wọn sọ̀rọ̀. Ati nípa ìgbàgbọ́ wọ́n ń bọ̀ wá tààrà sí àkaso ti Jákọ́bù nísinsìnyí, títí dé ẹsẹ̀ àgbélébùú, níbẹ̀ ni wọ́n n gbé gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn kalẹ̀ si, wọ́n sì ń wí pé, “Olúwa, eru eṣẹ yi poju, mio lee ruu mo. Oluwa jowo bami so ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ mi kúrò, kí o sì mú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ese kúrò nínú ọkàn mi. Kí èmi, nípa ìgbàgbọ́, lónìí yi, gbà ọ́ gẹ́gẹ́ bí Olùgbàlà mi. Áti láti ìsinsìnyí lọ, èmi yóò máa tẹ̀lé ọ ní gbogbo ibuso ní ọ̀nà yi, títí dé òpin ìrìnàjò náà. Mo rí ohun tí ó túmọ̀ sí láti ‘tẹ̀síwájú sí pípé,’ kíi se ki n má lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì ko, àti gbòǹgbò àwọn iṣẹ́ òkú bí ìtẹ̀bọmi àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Ṣùgbọ́n mo fẹ́ máa tesíwájú títí èmi yió fi di oku si ese, tí Kristi yóò sì lè wà láàyè nínú mi.”

Oúnjẹ Ojoojúmọ́
Ṣugbọn ẹ jẹ ki awa, bi a ti jẹ ti ọsán, mã wà li airekọja, ki a mã gbé igbaiya igbagbọ́ ati ifẹ wọ̀; ati ireti igbala fun aṣibori.
1 Tẹsalóníkà 5:8

An Independent Church of the WORD,