Ọ̀rọ̀ Ọjọ́ náà
July 30, 2026
60-0522E – Ìsodomo #4
Nígbà tí Kristiẹni bá kún fún ìhìnrere, tí ó kún fún oore Ọlọ́run, ati ti gbogbo ohun rere Ọlọ́run bati ngbe nínú rẹ̀, pẹ̀lú ọkàn tí ó ṣí sílẹ̀, tí ó setán láti ṣiṣẹ́, tí ó fẹ́ láti wà ní ipò omo, tí ó mura tan lati ṣe ohunkóhun tí Ẹ̀mí Mímọ́ ba ni ko ṣe, tí ó rekọjá láti inu ikú sí ìyè, tí ati sọ́ọ̀ di mimo kúrò nínú gbogbo nǹkan ayé, tí ó ń rìn nínú ìmọ́lẹ̀ bí ìmọ́lẹ̀ ṣe ń tan sọ́dọ̀ rẹ̀, tí ó ń tesíwájú, ó ti ṣetán niyen. Nígbà náà ni Ọlọ́run yóò ti ilẹ̀kùn mo awon ohun ayé lẹ́yìn rẹ̀, ni atipa, yióò sì fi edidi Ẹ̀mí Mímọ́ ti Olorun ti selérí dì í. Hallelujah! Titi di igba wo? Títí yió fi de ibi toń lọ. Enikeni ko gbodo gbe jáde mo lojú ọ̀nà oko ojú irin tabi ko ja edidi naa lati wo bóyá ohun gbogbo si wa daada lẹ́ẹ̀kan sí i. Ó ti dáa be, iwo saa fi í sílẹ̀. Olùṣàyẹ̀wò ti ṣe àyẹ̀wò rẹ̀. Titi d’igbawo ni a fi èdìdì dì ọ́? Títí di ọjọ́ ìràpadà rẹ ni a ti fi èdìdì naa dì ọ́.
Oúnjẹ Ojoojúmọ́
Ṣùgbọ́n ẹni tí o ba foriti títí dé òpin, òun náà ni a o gbàlà.
Matteu 24:13