Ọ̀rọ̀ Ọjọ́ náà
July 29, 2026
Ẹni tó tóbi ju Solomoni lọ wà níhín 57-0228
Ah, mo fẹ́ kí ẹ wo ohun daradára kan níbi yí. Nígbà tí Jésù bá nlé emi esu jáde, kekere bintin bayi lori loju Jesu debi wipe ìka rẹ̀ lásan lásan lofi nle emi esu jade. Gbogbo ohun tó ní láti lò koju yen lo. Ah, ìbùkún ni fún Orúkọ mímọ́ Rẹ̀. Ó kàn maa lo ìka kan soso lati le emi esu tó lágbára jùlọ tó lè dìde láti inú ina ọ̀run àpáàdì tó ń jó jade ni. Ìka kékeré kan ló máa fi lee jade. Koni se jubeelo. Ṣùgbọ́n nígbà tó bá ní odo àgùntàn tó sọnù tó ṣìnà, tó sì lọ mú un padà wá, ó máa mú un, asì gbé e lé èjìká Rẹ̀. Ibi tó lágbára jùlọ lara ènìyàn ní ẹ̀yìn àti èjìká rẹ̀. Ó sì máa ń mú eya ara tó lágbára jùlọ, kì í ṣe ìka rẹ̀ o, bí àgùntàn ba sọnù, ó máa ń gbee si èjìká Rẹ̀, ó sì máa ń fi pelepele gbé e padà s’agbo. Sugbon ìka kan ṣoṣo ni Jesu maá ń lo fun èṣù…
Oúnjẹ Ojoojúmọ́
Ẹnyin ti rò o si? bi ọkunrin kan ba ni ọgọrun agutan, bi ọkan nù ninu wọn, kì yio fi mọkandilọgọrun iyokù silẹ̀, kì yio lọ sori òke lọ iwá eyi ti o nù bi?
Matteu 18:12