Ọ̀rọ̀ Ọjọ́ náà
August 1, 2026
Ibatan Olùràpadà naa
60-1002
Àwọn omo Amẹ́ríkà ń hùwà bí ará Amẹ́ríkà, àwọn omo Jámánì ń hùwà bí ará Jámánì, nítorí pé ìyẹn ni ẹ̀mí orílẹ̀-èdè wọn. Àwa sì ní Ẹ̀mí orílẹ̀-èdè tiwa. Ẹ̀mí Mímọ́ to ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wa, láti ọ̀run, ìwọ náà ń si n hùwà bí omo orile ede yen. Ó ń mú kí o hùwà bí wọ́n ṣe ń ṣe níbẹ̀, nítorí pé ìwọ jẹ́ ti ayé mìíràn.
Looto awa ń gbé ní Amẹ́ríkà. Ìyẹn ninu ago ara. Ṣùgbọ́n ọkàn tí ń darí wa, ìwà wa, láti òkè wá ni. A ń gbé láti òkè wá nítorí pé a bí wa láti òkè wá. Gbogbo àwọn Kristẹni loti òkè wa. Jésù wí pé, “Èmi ko wa láti ìsàlẹ̀. Èmi wá láti òkè. Bí mo bá wa láti ìsàlẹ̀ ni, àwọn iranse mi ìbá jà fún mi. Ṣùgbọ́n ìjọba mi jẹ́ ti òkè.” Bẹ́ẹ̀ náà ni gbogbo ènìyàn tí a bí láti ìjọba Ọlọ́run, ó wá láti òkè wá.
Oúnjẹ Ojoojumo
Má bẹ̀ru, agbo kekere; nitori didùn inu Baba nyin ni lati fi ijọba fun nyin.
Lúùkù 12:32″