Ọ̀rọ̀ Ọjọ́ náà

Ọ̀rọ̀ Ọjọ́ náà
July 26, 2026

Ayaba Sheba 61-0119E

…bí ẹ̀ka àkọ́kọ́ ti àjàrà náà bá mú ìjọ ti Pentecosti jáde, gbogbo ẹ̀ka gidi láti inú àjàrà náà yóò mú ìjọ ti Pentecosti mìíràn jáde. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ka ní a ti lo papo mo igi ajara ti Pentecosti yi, wọ́n sì nso eso ara wọn. A lo ẹ̀ka ijo Methodisti sara ẹ̀, ẹ̀ka Baptisti, ẹ̀ka ljo to fi ifedefo ropo emi mimo, gbogbo irú ẹ̀ka mìíràn. Won si ń so èso arawon.

O lè mú igi osàn kí o sì lo eka igi àjàrà mo lara. Ounje towa láti inú igi náà ni yió maa je, ṣùgbọ́n yóò so èso àjàrà. Fi osan wewe sínú rẹ̀, yóò so osan wewe, koni ṣo eso osàn, síbẹ̀ óunje igi osàn lonje. Wo, èyíkéyìí èso osàn…

Ìjọ kijo tí ó bá njewo pé òun jẹ́ Kristẹni a ma je ninu ògo àti ìyìn Kristi. Ṣùgbọ́n kò lè so èso ti Kristi. Kò ní so eso ìyè ti Kristi afi igbatí Kristi yóò fi gbé ẹ̀ka náà jáde fúnra rẹ̀. Nígbà náà ni yóò—yóò kọ ìwé Ìṣe emimo ninu awon Aposteli mìíràn lẹ́yìn rẹ̀ (Bee nio), nítorí pé ó jẹ́ iṣẹ́ emi Mímọ́ nínú ìjọ. Ẹe ri? Bẹ́ẹ̀ ni ó rí ní asalẹ́ yìí, Jésù Kristi okan náà lánàá, lónìí, àti títí láé.

Oúnjẹ Ojoojúmọ́
Ṣugbọn nisisiyi ti a sọ nyin di omnira kuro ninu ẹ̀ṣẹ, ti ẹnyin si di ẹrú Ọlọrun, ẹnyin ni eso nyin si ìwa mimọ́, ati opin rẹ̀ ìye ainipẹkun.
Romu 6:22

An Independent Church of the WORD,