Ọ̀rọ̀ Ọjọ́ náà

Ọ̀rọ̀ Ọjọ́ náà
July 25, 2026

Ọlọ́run Nínú Àwọn Ènìyàn Rẹ̀
50-0227

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú wọn ló lóye rẹ̀. Àwọn ope ènìyàn fi tayotayo gbọ́ ọro Jesu. Bẹ́ẹ̀ gaan na lori lónìí. Ṣùgbọ́n mo ti kíyèsí àwọn ènìyàn; ofere je gbogbo àwọn ìjọ eleyameya lo máa ń wá sí àwọn ìpàdé mi. Koda an ri awon omo ijo àwọn agba, àwọn Júù, Giriki, ijo Aguda, àti onirunrú ijo. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò bọ̀wọ̀ fún ijo eleyameya kankan; Ó kàn bọ̀wọ̀ fún ìgbàgbọ́ tí ó wà nínú ẹnìkọ̀ọ̀kan ni. “Mo lè see, bí iwo ba gbàgbọ́,” Ni Jesu wí.

Lẹ́yìn náà Ó wí pé, “Lọ kí o má sì se dẹ́ṣẹ̀ mọ́, kí ohun ti o búrú ju eyi má baà sele sio.” Nítorí náà, láti gba ìwòsàn re, o gbọ́dọ̀ di Kristẹni lẹ́yìn tí o bati gbá iwòsàn re. Mo sì gbàgbọ́, mo fe sọ èyí, wipe abala meji ni etutu ti Jesu se pin si, nígbà tí a bá ti wòyin sàn tan, a dárí ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín bakanna. Mi ò gbọ́ ki ọ̀pọ̀lọpọ̀ yin se aamin si èyí, ṣùgbọ́n òtítọ́ ni. “Ẹ jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ yín fún ara yín, kí ẹ sì gbàdúrà fún ara yín, kí ẹ lè rí ìwòsàn.”

“Ẹ lọ kí ẹ má sì dẹ́ṣẹ̀ mọ́, kí ohun tí ó burú jù bẹ́ẹ̀ lọ maba bá yín.” Jesu wí pé, “Èwo ni ó rọrùn jù? Se lati sọpé a dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́, tàbí gbé akete rẹ kí o sì maa rìn ni?” Nkankan naa ni.

Oúnjẹ Ojoojúmọ́
Ẹ jẹwọ ẹ̀ṣẹ nyin fun ara nyin, ki ẹ si mã gbadura fun ara nyin, ki a le mu nyin larada. Iṣẹ ti adura olododo nṣe li agbara pupọ.
Jákọ́bù 5:16

An Independent Church of the WORD,