Ọ̀rọ̀ Ọjọ́ náà
July 24, 2026
Israeli àti Ìjọ #1 53-0325
Abrahamu gba ìlérí naa kí ó tó di pé a kọ ọ́ nílà. Lẹ́yìn náà, a fún un ní ìkọlà gẹ́gẹ́ bí èdìdì ìgbọràn ìgbàgbọ́ rẹ̀. Nígbà tí a bá sọ pé… Ìdí nìyẹn tí Billy Graham, Charles Fuller, àti Billings àti gbogbo wọn, ìdí tí wọ́n fi ń sọ̀rọ̀ nípa wọn, àwọn arákùnrin Baptist. Mo sọ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn bẹ́ẹ̀, Rufus Mosley àti gbogbo won beyen. Mo sọ pé…
Ó wí pé, “Nje o mo wipe a jere Okan ẹgbẹ̀rún lona ogún laarin ọ̀sẹ̀ méjì. Sugbon wọn kò rí ogún ènìyàn mo lehin naa
Mo so fun won wí pé, “Wọn kò ni iyípadà okan lofaa “
“Ó wí pé, “Sugbon wọ́n gba Kristi gẹ́gẹ́ bí Olùgbàlà won.”
Mo wí pé, “Ṣùgbọ́n, wọn kò ni iyípadà okan se. Bẹ́ẹ̀ ni o. O kò ni iyípadà títí…Atunbi túmọ̀ sí “láti yí padà.” Wo o, Paulu…
Peteru ti gba Oluwa gbo, a ti baptisi re, a ti fun ni agbara lati wo awon alaisan sàn, lati le awon emi esu jade, lati ji awon oku dide. Jesu si wifun un, ni ale ki a to kan an mo agbelebu pe, “Lẹhin ti aba ti yi e lokan pada tan, mu awon arakunrin re lokan le.” Se beeni? O ti ni igbala okan asi ti soo di mimọ, sugbon koi ti ni iyipada okan. Iwe Mimo niyen.
Ounjẹ Ojoojumọ
Ṣugbọn mo ti gbadura fun ọ, ki igbagbọ́ rẹ ki o má yẹ̀; ati iwọ nigbati iwọ ba si yipada, mu awọn arakunrin rẹ li ọkàn le.
Luku 22:32