The Seventy Weeks of Daniel Series banner

26-1122 Gabriel’s Instructions To Daniel

Àwọn eni ti ati pe Ìjáde Ọ̀wọ́n,

Kí Olorun tó ṣe etutu fese wa, kí a tó tú Ẹ̀mí Mímọ́ sori wa, kí a tó kọ gbogbo awon Màjẹ̀mú ti lae lae sílẹ̀, kò lè sí àfihàn awon omo Olorun.

Ó gbọ́dọ̀ dúró títí di àkókò yìí. Ó ń dúró de wòlíì Rẹ̀ ó sì ń dúró de wa!

Nísinsìnyí gbogbo nǹkan ń parí sí òkúta asiborí, sí àfihàn àwọn ọmọ Ọlọ́run tó ń padà bowa.

Ẹ̀mí Ọlọ́run bale angẹ́li Rẹ̀ alágbára osi see tó bẹ́ẹ̀ ge tí iṣẹ́ rẹ̀ sunmọ́ ti Kristi, debi wipé yóò so Òun àti Ijo Rẹ̀ papọ̀. Ọlọ́run ń fi àwọn ọmọ Rẹ̀ si ipo omo fún Ìgbasoke tó ń bọ̀.

Àkókò Àgbàyanu nla ní, bí Ẹ̀mí Mímọ́ ṣe ń bawa sọ̀rọ̀ tí Ó sì ń fi Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ hàn wa.

Àwọn isele ńlá ń ṣẹlẹ̀, nínú ayé, àti pàápàá jùlọ laarin Ìyàwó Kristi.

Àwọn ìjà àgbáyé wà nítòsí. A lè di eérú ní ìṣẹ́jú aaya. Ẹnikẹ́ni tó ní òye lè gbọ́ awon ìròyìn, ko teti gbọ́ àwọn olòṣèlú kí ó sì mọ̀ pé nǹkan kan ń bọ̀ wa sele. Ẹ̀rù ń ba àwọn ènìyàn layé.

Melòó ni ó gbọ́ àsọtẹ́lẹ̀ yìí, pé nínu osu kini odun, a ṣo àsọtẹ́lẹ̀ pé orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà àti Rọ́ṣíà yóò di eérú gbigbona?

Èyí ni ohun tí a nílò. Ó ti sunmo etile ju bí a ti ń rò lọ. Ẹ̀e rí? Nítorí náà, bí o bá sunmọ́ tó bẹ́ẹ̀ ti àwọn ènìyàn ayé yìí ń ṣo àsọtẹ́lẹ̀ pé isele nla yìo ṣẹlẹ̀, ó dára kí a máa ṣọ́ra, kí gbogbo nǹkan wà ní sepesepe, kí a se ijẹ́wọ́ gbogbo nǹkan, kí gbogbo nǹkan wà ní ìmúrasílẹ̀.

Nítorí a kò mọ̀ àkókò gan-an tí Olúwa wa yóò pè wá sodo ara.

Nígbà tí Ó bási pè wa “Ẹ gòkè wa sihin”, ó dára kí a wà ní ìmúrasílẹ̀. Yóò sì dé ní wákàtí tí ẹ kò rò.

Ẹ̀mí Mímọ́ wà láàárín wa, Ó ń bawa soro nípasẹ̀ wòlíì Rẹ̀, Ó ń múra wa sílẹ̀ láti gòkè kí a sì ré Jọ́dáànì koja.

A lóye nípa kíkà Ìwé àti gbígbọ́ Ohùn Rẹ̀ lórí àwọn fonran nipa awon ohun tó ń ṣẹlẹ̀.

Ọlọ́run ń sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ angẹ́li Rẹ̀ lórí àwọn fonran káàkiri àgbáyé láti tù àwọn ènìyàn Rẹ̀ nínú kí Ó sì sọ fún wọn pé, “A wà ní igba ikẹhin, ṣùgbọ́n ẹ má bẹ̀rù ayé yìí, nítorí pé Mo wà pẹ̀lú yín, àní NÍNÚ YÍN.

Ẹ̀yin ni Ọ̀rọ̀ Mi ti aso di ara. Ẹ kò ní ohun kankan láti bẹ̀rù.”

Fún opo oṣù sehin, Ó ti ní n fun wa ni ìdanilekọ̀ lori Ìwé Ìfihàn Jésù Kristi. A ti kọ nipa àwọn igbà ijo àti Ìfinisipo ọmọ, a sì ti tun ṣetán láti gbọ́ kí a sì kẹ́kọ̀ọ́ lori Àwọn Ọ̀sẹ̀ Àádọ́rin ti Daniel.

Lẹ́yìn náà ni Àwọn Èdìdì, Àwọn Iyonu, Àwọn Egun, àwọn Eṣú, obìnrin tó wà nínú oòrùn àti lile dragoni pupa naa sile. Sisedìdì awon eniyan oke meje ole egbaaji, àti bee bee lo.

Gẹ́gẹ́ bí Daniel, a ń kà a si ń gbọ́ ohun tí wòlíì sọpe yóò ṣẹle. Ìwé Mímọ́ ń ṣẹ.

Àkókò to to niyi fún Ìyàwó láti gbọ́ eyi pẹ̀lú ipò tí ayé wà lónìí.

Ati sedidi ijo Olorun. Àwọn ẹni búburú ń ṣe búburú sí i. Àwọn ijo ń wa nfi “ijo” sere sí i. Àwọn ènìyàn mímọ́ ń súnmọ́ Ọlọ́run si. Àwọn ẹ̀bùn Ẹ̀mí bẹ̀rẹ̀ sí í pọ̀ sí i nínú àwọn ẹgbẹ́ kékere naa. A wà ní opin aye.

A lóye wipé ní igbà ìkẹyìn ìyàn yóò mu, kì í ṣe fún oúnjẹ àti omi nìkan, ṣùgbọ́n fún gbígbọ́ Ọ̀rọ̀ Òtítọ́ Ọlọ́run.

Àwọn ènìyàn yóò lọ sí ìlà-oòrùn, ìwọ̀-oòrùn, àríwá àti gúúsù, wọ́n ń wá láti gbọ́ Ọ̀rọ̀ Òtítọ́ Ọlọ́run.

Àwọn ìjo yóò wà ní iyapa won asi tilekun mori tó bẹ́ẹ̀ tí wọn kò ní le gbọ́ o.

Ṣùgbọ́n a lóye nípasẹ̀ kíkà Ìwé Rẹ̀ àti gbígbọ́ Ohùn Rẹ̀ lórí àwọn fonran pé Ẹ̀ka kan yóò dìde láti idile Dáfídì. Ẹgbẹ́ kékeré yẹn yóò tẹ “play” wọ́n yóò sì gbọ́ Ohùn Ọlọ́run lórí àwọn fonran.

Ní ọjọ́ yìí, àdúrà naa ti gba.

Olúwa, a rí nípasẹ̀ àwọn Ìwé, pẹ̀lú Ìwé Rẹ̀ — Ìwé Ísáyà, Ìwé Jẹrẹmáyà, Ìwé Jákọ́bù, Jòhánù, Lúùkù, Máàkì, Mátíù, Ìwé Ìfihàn — gbogbo àwọn Ìwé Rẹ̀, pé a sunmọ́ opin aye.

A ti gbe ojú wa soke sí Ọ̀run, nínú àdúrà, nínú ẹ̀bẹ̀, láti rí ibi tí a wà, Olúwa. Ati bẹ̀rẹ̀ sí í rí ìmọ́lẹ̀ ọ̀sán tí ń yọ.

Àti pé, Olúwa, a wá sọ̀dọ̀ Rẹ. Ìgbàgbọ́ wa ń wo Ọ̀ nísinsìnyí. Ati pa gbogbo ẹrù to wuwo ti, gbogbo ẹ̀ṣẹ̀, gbogbo àìgbàgbọ́ kéekeké tó rọrùn láti dimo wá, a ń tẹ̀ síwájú sí àmì ìpè gíga, tí a mọ̀ pé àkókò die lani lo.

Bí ibẹ̀rù ṣe ń kún inu ayé tí wọ́n sì ń gbìyànjú láti múra sílẹ̀ fún ohun tó ń bọ̀ nípa títòjú oúnjẹ pamo, a pè yín wá jẹ oúnjẹ Mánà ti afi pamọ́ tí Ò ti se tí Ó sì ti ko pamọ́ fún Ìyàwó Rẹ̀.

Arákùnrin Joseph Branham

Ìwaasu: 61-0730M
Àwọn Ìtọ́ni Gabriel fún Danieli
Àkókò: Ọjọ́ Àìkú, 12:00 ọ̀sán, àkókò Jeffersonville
Ìwé Mímọ́:
Orin Dafidi 99, iwe
Ìfihàn 1–3
Jẹrẹmáyà 32
Iwe ifihàn 5:8–14
Jẹrẹmáyà 25:8–17
Danieli 9
Mátíù 24:15
Ìfihàn 7