26-0920 Iru adamodi

Ẹyin 1 nínú TM, (TheM, Tape Ministry Ed.)

Nígbà tí àwọn ènìyàn bá nbi wá pé:

Ìbéèrè: Ṣé o je ọ̀kan lára ​​wọn tí wọ́n gbàgbọ́ pé Ọlọ́run rán William Marrion Branham láti pe ìyàwó Ọlọ́run?

Ìdahun: BẸ́Ẹ̀NI, Èmi je ọ̀kan lára ​​wọn.

Ìbéèrè: Ṣé o gbà gbogbo ọ̀rọ̀ tí a sọ lórí wọn gbo?

Ìdahun : Hallelujah, Èmi je ọ̀kan lára ​​wọn.

Ìbéèrè: Nígbà náà o gbọ́dọ̀ gbàgbọ́ pé o gbọ́dọ̀ tẹ Play kí o sì gbọ́ ohùn Rẹ̀ láti jẹ́ ìyàwó Kristi?

Ìdahun : Ògo nifun Olorun, Emi gan-an niyen, emi gaan nìyẹn ni èmi dé gbàá de góńgó…Èmi je ọ̀kan lára ​​wọn.

Ìbéèrè: Ṣé o ń sọ fún mi pé, o gbàgbọ́ ní tòótọ́ pé ìwọ ni irú ọmọ Ọba tí a yàn, tí a yàn, tí a ti yàn tẹ́lẹ̀ láti ìpìlẹ̀ ayé láti gba Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ gbo, láti jẹ́ ìyàwó Rẹ̀, tí a sì pé ní ojú Rẹ̀, láìsí ẹ̀ṣẹ̀ kankan, àti pé a kò lè tàn ọ́ jẹ?

Ìdahun: Hallelujah, oo gbọ́, iyẹn ni mi 110%, MO JẸ́ Ọ̀kan ninu wọn.

Gẹ́gẹ́ bí Jésù fúnra rẹ̀ ti wi àwa ni ìtumọ̀ Ọ̀rọ̀ Rẹ̀. Àwọn ọmọ Ìjọba naa. Ìfarahàn Ẹ̀mí Mímọ́. Irú-ọmọ Ìjọba ti àkókò yìí.

Ṣé o mọ̀? Ó tó àkókò fún gbogbo ènìyàn láti mọ ẹni tí a jẹ́ gan-an, nítorí náà kò sí àṣìṣe kankan. A ó jẹ́ kí Ọlọ́run sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ wòlíì Rẹ̀, kí ó sì kó gbogbo rẹ̀ jọ fún yín.

Agbára kan náà tí ó sọ ayé di alààyè wà nínú àwọn ènìyàn tí ó ní Ẹ̀mí Mímọ́. Bẹ́ẹ̀ ni. _Àwọn ọkùnrin àti obìnrin, ó tó àkókò tí a ó fi mọ ẹni tí ẹ jẹ́. Satani ń ngbìyànjú láti fi yín pamọ́, kí ó sọ fún yín pé ẹ jẹ́ ohun kan tí a ti dẹ́rù bà. Ẹ̀yin kì í ṣe bẹ́ẹ̀. Ẹ̀yin jẹ́ ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin Ọlọ́run.

Ọlọ́run kò sí ní ọ̀run, ó wà nínú yín. Hallelujah !

Ìdahun: Ọlọ́run kò sí ní ọ̀run, ó wà láàyè, ó sì ń gbé nínú olúkúlùkù wa!

Pẹ̀lú ọjọ́ tuntun kọ̀ọ̀kan, pẹ̀lú gbogbo èémí tí a ń gbà, Ìfihàn tí Ó ti fún wa nípa ẹni tí a jẹ́ ń pọ̀ sí i. Àwa ni Ọ̀rọ̀ alààyè tí ń gbé nínú ara.

Àwa mọ̀ èyí nítorí Ó ti fún wa ní Ìfihàn tí Ó rán ní ọjọ́ wa; ẹni tí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ sọ pé Òun yóò rán láti wàásù àti láti kọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Rẹ̀ nínú Ìfihàn 22.

Èmi Jesu ti rán áńgẹ́lì mi láti jẹ́rìí fún yín nípa àwọn nǹkan wọ̀nyí nínú àwọn ìjọ.

Ó rán áńgẹ́lì Rẹ̀: William Marrion Branham, láti sọ̀rọ̀ nínú àwọn ìjọ Rẹ̀…Èyí túmọ̀ sí pé ọ̀rẹ́ mi ńte àwọn fonran nínú àwọn ìjọ Rẹ̀. Èyí kò tilẹ̀ gba ìfihàn, o kàn ní láti kaà ni.

Gẹ́gẹ́ bí Ọ̀rọ̀ náà ti wí, àkókò yìí ni àkókò ẹ̀tàn jùlọ nínú ìtàn ayé. Ẹ̀mí òtítọ́ àti èké yóò sún mọ́ ara won débi pé yóò tan àwọn àyànfẹ́ náà jẹ bí ó bá ṣeé ṣe.

Ọlọ́run rán Áńgẹ́lì Rẹ̀ sí àwọn ìjọ. A ní Ohùn Rẹ̀ ní ìka ọwọ́ wa. A lè gbọ́ Ọ̀rọ̀ fún Ọ̀rọ̀ ní pàtó ohun tí Ó sọ. Kò nílò àlàyé tàbí ìtumọ̀ kankan, gbogbo ohun tí Ìyàwó ní láti ṣe ni kí ẹ tẹe GBÀDÚRÀ kí ẹ sì GBÀGBỌ́.

Ó kìlọ̀ fún wa pé, ẹ má ṣe yí gbolohun kan tàbí àkọlé kan padà lorí àwọn fonran náà. Ẹ má ṣe fi òye yín tàbí èrò yín sii, ẹ gbọ́ ohùn mi kí ẹ sì gbàgbọ́. Títí di òní yìí, ìyẹn kò ṣeé ṣe; ṣùgbọ́n lónìí ó jẹ́ nítorí pé ọ̀nà tí Ọlọ́run pèsè fún òní ni.

A ṣẹ̀ṣẹ̀ gbọ́ nípa Ìgbà Ijo Méje àti bí ó ṣe jẹ́ pé làti ibere titi de opin akoko, àwọn ẹ̀mí wọ̀nyẹn dìde láti mú àwọn ènìyàn kúrò nínú Ọ̀rọ̀ òtítọ́. Báwo ní àkókò kọ̀ọ̀kan, lẹ́yìn tí ìránṣẹ́ náà ba ti lọ, bi wọ́n ṣe mú àwọn ènìyàn lọ sí ìgbàgbọ́ tàbí ẹ̀kọ́ adamo; sí ara wọn àti èrò ènìyàn.

Lónìí wọ́n gbìyànjú láti pa agbára wa run wọ́n sì wí pé, “Ó, wọ́n gbàgbọ́ pé àwọn foran náà ni Ohùn pàtàkì jùlọ tí ẹ gbọ́dọ̀ gbọ́. Ẹ gbọ́dọ̀ fi awon fonran naa kọ àwọn eniyan nínú ìjọ yín…ìyẹn jẹ́ ọ̀rọ̀ asiwere. Arákùnrin Branham kò sọ pé kí ẹ maa fi awon fonran naa kọ àwọn eniyan ní ṣọ́ọ̀ṣì. Nísinsìnyí, ohùn iṣẹ́ ìránṣẹ́ ni ẹ gbọ́dọ̀ gbọ́.”

Ni temi o, ìyẹn ni irúgbìn ìyàtọ̀! O GBODO TẸ̀ PLAY PLAY ki o si gbọ Ohùn Ọlọrun ninu awọn ijọ yin nitori Ohùn kanṣoṣo ti Ọlọrun funra Rẹ dmfowosi niyen. O gbọdọ gbọ gbogbo Ọrọ ti Ọlọrun sọ.

Emi Jesu ti ran angẹli mi lati jẹri awọn nkan wọnyi fun yin ninu awọn ijọ.

Angẹli ti a ti fi idi re mule yẹn n sọrọ ninu ijọ wa, nitorinaa mo pe yin lati wa darapọ mọ wa lati gbọ Ohùn yẹn pẹlu Iyawo Rẹ lati gbogbo agbaye lori ipade ni agogo 12:00 osan, akoko Jeffersonville, ki o si gbọ: 65-0118 – “Iru adamodi”.

Arakunrin Joseph Branham